Ile ọti ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yinbọn pa Tajudeen si n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, to ṣẹṣẹ pari yii, ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lọọ ka ọmọkunrin kan, Tajudeen mọ ile ọti, ti wọn si yinbọn pa a sibẹ.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni wọn ya bo ile ọti to jẹ ti ọkunrin ti wọn pa yii to wa ladojukọ I. G. S, Sawmill, niluu Ilọrin. Bi wọn ṣe debẹ ni wọn pe e jade, ni wọn ba yinbọn pa a.

Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ to ba oniroyin wa sọrọ, Ọgbẹni Abdul Malik, sọ pe awọn ọrẹ oloogbe yii kan lo n ṣe ọjọ ibi lọjọ naa, ti wọn si n lo ile ọti rẹ fun ayẹyẹ. Yatọ si ile ọti ti oloogbe yii ni, a gbọ pe o tun n ta ọkọ tokunbọ to maa n lọọ gbe wa lati orile-ede Olominira Bẹnin.

Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si sọ pe iwadii n lọ lọwọ lori rẹ.

Leave a Reply