Ile Tinubu ni London di Mẹka fawọn oloṣelu, Ibikunle Amosun naa ti lọọ ki i

Faith Adebọla

Ṣe wọn ni ẹni ta o fẹ nile ẹ n jinna, afi bii ẹni rin irin-ajo lọ silẹ mimọ, boya Mẹka tabi Jerusalem, tawọn ẹlẹsin fi maa n jagba lati lọ, lawọn oloṣelu n tẹkọ leti lọọ ṣabẹwo si agba ọjẹ oloṣelu Aṣiwaju ẹgbẹ APC nni, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, niluu London, lorileede UK, nibi to ti n gba itọju, to si ti n fara nisinmi lati bii oṣu meji sẹyin.

Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ ri ati aṣofin agba to n ṣoju ẹkun idibo apapọ Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ogun nileegbimọ aṣofin apapọ l’Abuja, Sẹnetọ Ibikunle Amosun naa ti lọọ yọju si Tinubu niluu oyinbo, lati beere alaafia ẹ.

Ba a ṣe gbọ, yatọ si ti ọrọ ilera, wọn lawọn mejeeji tun jọọ sọrọ nipa ẹgbẹ APC ati awọn nnkan to n ṣẹlẹ lagbo oṣelu lọwọlọwọ nilẹ wa, lẹyin ijiroro wọn ni Amosun ati Tinubu ya fọto lati fi han pe ọkọ Olurẹmi wulẹ n fara nisinmi ni, ko si aarẹ kan to n da a laamu.

Lati ọsẹ diẹ sẹyin ti Tinubu ti wa ni London, nibi to ti lọọ gba itọju lawọn eeyan nla nla lagbo oṣelu ati ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti n ṣabẹwo si i, ti wọn si n jabọ pe Tinubu ko si nidubulẹ aisan rara o, bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ wọn maa n yọ lọ ni, wọn ki i jẹ keti meji mẹta mọ si abẹwo naa ki wọn too lọ.

Aṣofin James Faleke, Aarẹ Muhammadu Buhari, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, tipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, t’Ondo, Rotimi Akeredolu atawọn aṣofin Eko mẹrin kan ti olori wọn, Mudaṣiru Ọbasa, ko sodi, wa lara awọn ti wọn ti lọọ ki Tinubu ni London, lati ṣe baba naa ni ‘kara o le o’.

Leave a Reply