Stephen Ajagbe, Ilorin
Obinrin alaboyun kan tawọn eeyan mọ si Funmi ati agbalagba kan ti wọn n pe ni Iya Isanlu, ni atẹgun ojo pa sinu ṣọọṣi niluu Kajọla, nijọba ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni nnkan bii aago marun-un ku iṣẹju mẹẹẹdogun, lọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun yii, nileejọsin Boluwarin.
Alukoro ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, ẹka ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe atẹgun ojo naa ka wọn mọ ibi tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ibẹ lo wo orule pa wọn si.
Afọlabi ni wọn ti gbe oku awọn mejeeji lọ si mọṣuari ilewosan ijọba.
O tẹsiwaju pe awọn eeyan bii mẹwaa lo tun fara pa ninu iṣẹlẹ naa, wọn si ti n gba itọju.
O ni atẹgun ojo naa tun sọsẹ lawọn agbegbe kan bii Egosi-Ile, nibi to ti wo awọn opo ina lulẹ, to si sọ gbogbo ilu sinu okunkun. Bẹẹ lo tun ṣẹlẹ niluu Odo-Ọwa, orule aagọ ọlọpaa to wa nibẹ ni atẹgun naa gbe danu patapata.