Ilẹ ya bo ọpọlọpọ awọn awakusa lojiji, nibi ti wọn ti n wa goolu lai gbaṣẹ

Faith Adebọla

Ọgọọrọ eeyan tẹnikan o ti i le sọ pato iye wọn, titi kan awọn majeṣin, lo pade iku ojiji lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, nigba ti yeepẹ ya bo wọn mọlẹ nibi ti wọn ti n wa kusa goolu lai gbaṣẹ.

Ibi iwakusa kan ti wọn n pe ni Tojir, lagbegbe Duejime, nitosi ilu Anyiin, to wa nijọba ibilẹ Logo, nipinlẹ Benue, la gbọ pe iṣẹlẹ ibanujẹ naa ti waye.

Ọkunrin kan tọrọ naa ṣoju rẹ, Baba Ngutor, sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), pe ọpọ eeyan niṣẹlẹ naa sọ doloogbe, oku mẹta pere ni wọn ṣi ri fa yọ ninu koto giriwo ti wọn ti n wa kusa ọhun, nigba ti ọpọ awọn mi-in to fara pa ti wa nileewosan kan niluu Anyiin.

Ngutor sọ pe ọpẹlọpẹ ẹnikan tori ko yọ, nigba to ja raburabu labẹ yeepẹ diẹ to bo o lẹsẹ, oun lo sare wa saarin ilu, to si kegbajare pe gudugbẹ ti ja nibi tawọn ti n wa kusa naa.

Eyi lo mu awọn gende atawọn ọdẹ agbegbe naa sare lọọ doola ẹmi awọn eeyan ọhun, ṣugbọn iwọnba diẹ ni wọn ri fa jade, ọpọ wọn ti dẹni akọlẹbo pẹlu ẹbiti yeepẹ to ya lu wọn ọhun.

Wọn l’Alaga ijọba ibilẹ Logo, Ọgbẹni Terseer Agber, sọ lori foonu pe oun mọ nipa akitiyan awọn awakusa naa, ko si ṣeni to gba aṣẹ tabi iyọnda lọwọ ijọba ibilẹ tabi tipinlẹ ti wọn fi lọọ huwa ọdaran to ṣekupa wọn yii.

Alaga naa ni ọpọ awọn awakusa ni wọn n ja ijọba lole, ti wọn n lọọ wa a lọna ti ko bofin mu. O lọpọ igba lawọn ti ṣe ilanilọyẹ fawọn araalu atawọn ajeji lori ọrọ yii, ṣugbọn eti ikun lawọn kan lara wọn n kọ si i.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue, Abilekọ Catherine Anene sọ pe oun ṣẹṣẹ n gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni, ati pe awọn yoo ṣe iwadii to yẹ lori ajalu ọhun.

Leave a Reply