Ileeṣẹ aṣọbode mu kẹkẹ maruwa atọkọ bọọsi awọn fayawọ

Stephen Ajagbe, Ilọrin
Ileeṣẹ aṣọbode ilẹ yii, ẹka tipinlẹ Kwara, ti ṣafihan awọn kẹkẹ maruwa kan pẹlu apo irẹsi mẹwaa tawọn onifayawọ ko sinu ẹ.

Bakan naa ni wọn tun ṣafihan awọn ọkọ bọọsi mi-in ti wọn fi n ṣe iṣẹ fayawọ.

Awon boosi ti won fi n se fayawo

Lara awọn ohun tileeṣẹ aṣọbode tun ṣafihan lonii, Ọjọru, Wẹsidee, niluu Ilọrin, ni awọn ọkọ bọọsi akero meje ti wọn kun fun apo irẹsi bamubamu, awọn ọkọ Toyota mẹfa ati ọkọ pikọọpu kan.

Laarin oṣu karun-un si oṣu kẹfa, ọdun yii, tijọba fofin de irin-ajo lọwọ tẹ awọn ẹru ofin naa.

Leave a Reply