Ileeṣẹ Dangote tu aṣiri nla: NNPCL ko ni irinṣẹ ti wọn fi le da ayederu epo bẹntiroolu mọ

Adewale Adeoye

Ba a ba dakẹ, tara ẹni aa ba ni dakẹ, nileeṣẹ ifọpo to ṣẹṣẹ bẹrẹ nilẹ wa, Dangote refinery fọrọ ọhun ṣẹ pẹu bi ileeṣẹ Dangote ṣe pariwo sita laipẹ yii pe ijọba orileede yii ko ni ojulowo irinṣẹ igbalode gidi lọwọ ti wọn fi le mọ iru epo bẹntiroolu tawọn alagbata ọja epo n gbe wọ orileede yii boya ayederu ni tabi ojulowo, eyi to si le ṣakoba fun awọn mọto atawọn injinni to n lo epo bẹntiroolu nilẹ wa.

O ni ọpọ epo tawọn alagbata ọja epo yii n gbe wọlu wa lo jẹ gbantu-ẹyọ, ti ki i ṣe ojulowo bii ti eyi to n jade lati ileeṣẹ Dangote rara.

Gẹgẹ bi Dangote ṣe wi, ‘‘Ko si awọn irinṣẹ igbalode kankan lọdọ NNPC ti wọn fi le mọ iru epo bẹntiroolu tawọn alagbata ọja epo n gbe wọlu wa, awọn epo ti ki i ṣe ojulowo ni wọn n lọọ ra wa silẹ wa bayii. Wọn mọ-ọn-mọ ṣe bẹẹ lati fi ba ọja jẹ fun ileeṣẹ mi ni. Mo ti kede iye ta a n ta epo bẹntiroolu fawọn onitirela ati iye ta n ta a fawọn to maa waa fọkọ oju omi gbe e lọ sọdọ awọn ti yoo ta a sita. Ṣugbọn nitori ere ajẹju lo jẹ kawọn kan lọọ lẹdi apo pẹlu awọn oniṣowo lagbaaye, ti wọn fi n gbe ayederu ọja epo bẹntiroolu wọlu wa bayii.

Bẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni ileeṣẹ epo Dangote gbe atẹjade kan jade latẹnu ọga agba pata fun eto iroyin nileeṣẹ naa, Ọgbẹni Anthony Chiejina, nibi to ti sọ pe ileeṣẹ NNPC ti lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan lati da ileeṣẹ ifọpo kan silẹ nitosi ibi ti ile ifọpo awọn wa. O ni awọn ileeṣẹ naa ko ni awọn eroja to peye lati maa fọ epo, ati lati mọ bi epo naa ṣe kun oju oṣuwọn to. Anthony ni awọn n sọ eleyii sita kawọn eeyan ma baa sọ pe ileeṣẹ Dangote lo n gbe epo ti ko kun oju oṣuwọn jade pẹlu bo ṣẹ jẹ pe itosi awọn ni wọn da ileeṣẹ ifọpo ọhun silẹ si. Ọkunrin naa ni awọn ko mọ ohunkohun nipa rẹ.

Lọsẹ to kọja ni Aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati ẹgbẹ awọn gomina nilẹ wa sọrọ pe ki NNPC yee mu owo ile lọ sita, ki wọn maa gba epo nileeṣẹ Dangote. Awọn eeyan naa ni ko si anfaani ninu ka maa na owo ile sita, nitori nipa rira epo lọwọ ileeṣẹ yii yoo din owo ti wọn n lọọ fi fọ epo l’Oke-Okun ku, bẹẹ ni iṣẹ yoo tun wa fun awọn ọdọ ilẹ wa lati ṣe.

Ṣugbọn titi di ba a ṣẹ n sọ yii, ileeṣẹ NNPC ati ẹgbẹ awọn alagbata epo bẹntiroolu ko ti i dahun si aṣẹ ti Aarẹ Bọla Tinubu atawọn gomina pa.

Leave a Reply