Ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori iku Dapọ Ọjọra, ẹgbọn iyawo Bukọla Saraki

Jide Alabi

Arabinrin Toyin Saraki ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati mọ bi ọrọ iku Dapọ Ọjọra ṣe jẹ.

Aburo ni Toyin, iyawo Saraki yii, jẹ si Dapọ Ọjọra to para ẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ti iroyin ọhun si ti da awuyewuye silẹ.

Ni gbọgbo ọjọ Abamẹta, Satide, ti iroyin ọhun gbalu, ibọn ni wọn sọ pe Dapọ Ọjọra yin lu ara ẹ ninu ile to n gbe ni Ikoyi, l’Ekoo, ti ọkunrin naa si dagbere faye loju-ẹsẹ.

Lojiji ni wọn sọ pe awọn eeyan ti wọn jọ n gbe gbọ iro ibọn, nigba ti wọn yoo si fi sare de ibi to wa, ninu agbara ẹjẹ ni wọn ti ba Dapọ.

Ni kete ti iṣẹlẹ ọhun ti waye loriṣiriiṣii iroyin ti gba igboro, bi awọn kan ṣe n sọ pe niṣe ni ẹgbọn Toyin Saraki yii yinbọn funra ẹ lori, bẹẹ lawọn mọlẹbi n sọ pe ki i ṣe pe o para ẹ o, aṣita ibọn lo pa a.

ALAROYE tun gbọ pe ni nnkan bii ọdun mẹsan-an sẹyin ni Ọtunba Adekunle Ọjọra, eni ti i ṣe baba ọkunrin to yinbọn para ẹ yii ti kọkọ padanu ọmọ ẹ ọkunrin ti wọn pe orukọ ẹ ni Gboyega Ọjọra, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Gbẹgi. Bakan naa ni wọn tun sọ pe ori ti kọkọ ko Dapọ yii yọ lasiko to ni ijanba pẹlu ọkada olowo nla kan ti wọn n pe ni Power Bike ni nnkan bii ọdun meloo kan sẹyin.

Ṣa o, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti sọ pe ki awọn eeyan ma gba iroyin to kọkọ gba igboro kan pe niṣe lọkunrin naa yinbọn pa ara ẹ gbọ rara. Ati pe komiṣanna fawọn ọlọpaa l’Ekoo, Kayọde Odumosu, ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ, awọn ọlọpaa yoo si fi eyi to jẹ ootọ mulẹ laipẹ yii.

 

Leave a Reply