Ileeṣẹ ọlọpaa doola eeyan meji lọwọ awọn ajinigbe ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Orin ọpẹ lo gbẹnu awọn arakunrin meji kan, Samuel Faremi ati Emmanuel Adeyẹmi, ti awọn ajigbe ji gbe ni  Obbo Ayegunlẹ, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa doola wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lai fara pa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, lo ti ṣe ẹkunrẹrẹ alaye lori iṣẹlẹ ọhun. O ni awọn ti wọn ji gbe mejeeji ọhun ni wọn jẹ ọmọ agboole Ilawẹ, niluu Obbo Ayegunlẹ, nijọba ibilẹ Ekiti. Awọn ajinigbe ya bo ile ti wọn n gbe, wọn n yinbọn soke, ti ibọn si n ro lakọlakọ, lasiko naa ni wọn ji awọn mejeeji gbe lọọ.

O tẹsiwaju pe o ku diẹ awọn ẹọ alaabo de ọdọ awọn ajinigbe ọhun ni wọn sa lọ, ti wọn si fi awọn ti wọn ji gbe silẹ pẹlu ibọn Ak-47, atawọn ohun ija oloro miiran. Ni bayii, awọn mejeeji ti wọn ji gbe ọhun ti darapọ mọ mọlẹbi wọn, ti wọn si ti lọ ṣe ayẹwo nileewosan, wọn ni ara wọn da aka.

 

Leave a Reply