Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu awọn ọmọ keekeke to n ṣe ẹgbẹ okunkun l’Ekoo

Aderohunmu Kazeem

Awọn ọmọ keekeke ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti wọn n fi ẹgbẹ okunkun da wahala silẹ nipinlẹ Eko ti wa latimọle ọlọpaa bayii.
Awọn ẹni afurasi ọhun bii mẹtala lọwọ ọlọpaa tẹ lori ẹsun idaluru ati ṣiṣe ẹgbẹ okunkun.
Agbegbe Muṣin ati Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni wọn ti mu wọn.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Muyiwa Adéjọbí, sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, pe aṣẹ Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ekoo, Hakeem Odumosu, lawọn tẹle nigba ti wahala awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ko jẹ ki awọn eeyan sinmi mọ lawọn àdúgbò kan niluu Eko.
O ni, “Kọmiṣanna ti paṣẹ pe ẹnikẹni ti a ba kẹẹfin pe o n ṣe ipata, idaluru tabi ẹgbẹ okunkun la gbọdọ mu, ko si foju wina ofin. Iyẹn lo ṣokunfa bi ọwọ ṣe tẹ awọn eeyan kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun lasiko ti wọn da wahala silẹ lagbegbe Morolukẹ, ni Muṣin, lọjọ kẹjọ, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni deede aago mẹwaa alẹ.
“Lara awọn ti ọwọ tẹ niwọnyi, Daniel Adome, ọmọ ọdun mejidinlogun; Popoọla Michael, ẹni ogun ọdun; Kayọde Thomson, ẹni ọdun mejidinlogun; ati Taiwo Okiki, ẹni ọdun mejidinlogun.”
Ẹgbẹ okunkun kan ti wọn pe n ni Kasari ni wọn ni awọn ọmọ ọhun n ṣe.
Muyiwa fi kun un pe ọwọ tun tẹ awọn mi-in ti wọn pera wọn lọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ni deede aago mejila kọja isẹju mẹẹẹdogun loruganjọ ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, lagbegbe Ikorodu, l’Ekoo.
O lawọn ọlọpaa Ipakodo lo ya lu wọn bíi iji, ti wọn sì ko wọn lọ sí teṣan wọn.
Lara awọn tọwọ tẹ ọhun ni Ọpẹ́yẹmí Ọdẹrinde, ẹni ọdun mọkandinlogun, Otubu Samson, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Otako Jeremiah, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; Kayọde Agoro, ọmọ ọdun mẹtadinlogun; Agbelusi Sunday, ẹni ogun ọdun; Kazeem Ishọla, ẹni ogun ọdun; Ọlaṣojo Gbọlahan, ọmọ ọdun mejidinlogun; Ayọdele Ọlasunkanmi, ọmọ ọdun mejidinlogun; ati Segun James, ẹni ọdun mọkanlelogun.
Awọn irinṣẹ buruku ti wọn ba lọwọ wọn ni, ibọn ilewọ, ọta ibọn, oogun abẹnu-gọngọ loriṣiiriṣii, aake, ada atawọn irinṣẹ ti wọn le fi gbẹmi eeyan.

Leave a Reply