Ileeṣẹ ọlọpaa ti ri awọn oṣiṣẹ tawọn ajinigbe ji gbe ninu oko ni Kwara gba pada

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ileeṣẹ ọlọpaa ti doola awọn oṣiṣẹ mẹta kan tawọn ajinigbe ji gbe labule Pampọ, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara.

Awọn oṣiṣẹ naa; Dokita Julius Owoẹyẹ, Akeem Ajadi ati Bọla Adedoye, ni wọn n ṣiṣẹ ninu oko Bafford ati Morola, ni Ẹlẹga, lasiko tawọn agbebọn kan ya bo wọn, ti wọn si gbe wọn lọ.

Lẹyin iṣẹlẹ naa, awọn ajinigbe naa beere fun miliọnu marundinlaaadọta naira ko too di pe wọn le yọnda wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ajayi Ọkasanmi, ni Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn ikọ ti Ọga ọlọpaa, Mohammed Bagega, da sita doola wọn lahaamọ awọn to ji wọn gbe.

Ọkasanmi ni ṣe ni awọn ajinigbe naa fi awọn eeyan naa silẹ nigba ti wọn ri i pe awọn ọlọpaa ti ya bo agbegbe ti wọn wa, ti wọn si sa lọ patapata.

O ni awọn ṣi n gbiyanju lati ri i pe ọwọ tẹ awọn ajinigbe naa.

Ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn ajinigbe bii mẹfa ti wọn dihamọra ya bo agbegbe naa, ti wọn si gbe awọn eeyan naa lọ.

ALAROYE gbọ pe aṣọ ọmọ ogun, ṣọja, lawọn ajinigbe naa wọ wa pẹlu ọkọ jiipu Hilux kan, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke lakọlakọ lati da ẹru bolẹ.

Leave a Reply

//outrotomr.com/4/4998019
%d bloggers like this: