Ọlawale Ajao, Ibadan
Gbogbo awọn ọlọpaa ti wọn kopa ninu iṣẹlẹ buruku to waye niluu Ogbomọṣọ, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti mu, ti wọn si ti bẹrẹ ijiya ẹṣẹ wọn ninu atimọle bayii.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii ninu atẹjade ti Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, SP Adewale Oṣifẹṣọ, fi ṣọwọ si akọroyin wa n’Ibadan, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọla Hamzat, fidi ẹ mulẹ pe awọn ti fi panpẹ ofin gbe awọn ọlọpaa to kopa ninu iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn ọlọpaa lọ sibi iṣẹlẹ yẹn nitori bi oludari ileegbafẹ kan laduugbo Under G, niluu Ogbomọṣọ, ṣe pe wọn ni ipe pajawiri pe awon ọmọ ẹgbẹ okunkun n daamu awọn onibaara awọn, wọn si n ba awọn dukia ileegbafẹ awọn jẹ.
“Laasigbo yẹn tubọ le si i nigba tawọn agbofinro debẹ, ti awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun naa si dina mọ wọn, ti wọn o fẹ ki wọn raaye wọle.
“Nibi ti ojo ibọn ti n rọ lọtun-un losi lọdọ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun, ati eyi ti awọn ọlọpaa n yin soke lati le awọn ero iworan jinna, ni ibọn ti ba Damilọla Iyanda, to jẹ Ọlọrun nipe, ati aburo rẹ, Fẹmi Iyanda, to fara pa. Ṣugbọn ara rẹ ti balẹ bayii, o si ti kuro nileewosan”.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun (22), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni wọn yinbọn paayan kan, ti eeyan meji si fara ṣeṣe rẹpẹtẹ nibi ija to waye laarin awọn ọmọ jayejaye kan lalẹ ọjọ naa.
Ṣugbọn dipo inu ọgba Fasiti Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH), ti wọn ti kọkọ ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, ileegbafẹ kan to wa laduugbo ti wọn n pe ni Under G, lọna Owode, nigboro ilu Ogbomọṣọ, nija buruku ọhun ti bẹ silẹ laarin awọn ọdọmọkunrin alafẹ kan.
ALAROYE gbọ pe nigba tawọn ọlọpaa de sibẹ lati pẹtu saawọ ọhun ni laasigbo ọhun tubọ fọnna soju nigba ti ọmọkunrin oníjà naa ti wọn pe lọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun n yinbọn, ti awọn agbofinro paapaa n yin, nigba naa lọkan ninu awọn ọlọpaa ti wọn pe sibẹ lati waa pẹtu sija ọhun yinbọn pa ọkunrin kan to n jẹ Iyanda Damilọla.
Ọkan ninu awọn meji ta a gbọ pe ori ko yọ lọwọ iku lẹyin ti ọta ibọn ba wọn ni wọn pe ni Iyanda Fẹmi Israel, ẹni to ti kẹkọọ jade nileewe LAUTECH lati ọdun diẹ kan sẹyin.
Lọjọ kẹta ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, lawọn alaṣẹ fasiti naa ti sọ pe ki i ṣe inu ọgba ileewe naa niṣẹlẹ ọhun ti waye, ati pe ẹni ti wọn yinbọn pa ọhun ki i ṣe ọmọ ileewe awọn.
CP Hamzat fidi ẹ mulẹ pe ninu ahamọ, lẹẹka ti wọn ti n tọpinpin iṣẹlẹ ọdaran, labẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, eyi to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, lawọn ọlọpaa ti wọn kopa nibi iṣẹlẹ iyinbọn-paayan naa wa bayii, nigba ti iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ to gbẹmi eeyan ọhun.