Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji kan, Abdulrahman Kadri, to ja ileeṣẹ to n ti n ṣiṣẹ lole niluu Ilọrin, iyẹn Jiajia Mate Furniture, to wa lọna papakọ ofurufu, lagbegbe Odota, lo ko si pampẹ ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, tipinlẹ Kwara.
Abdulrahman to n gbe l’Opopona Ogunṣọla, lagbegbe Asa-Dam, niluu Ilọrin, lọwọ tẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pẹlu irinṣẹ ileeṣẹ naa to gbe pamọ sinu apo kan, to si gbiyanju lati gbe e sa lọ.
Alukoro NSCDC nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe nibi ti afurasi naa ti fẹẹ gbe kinni ọhun jade l’okete ti boru mọ ọn lọwọ.
O ni lasiko tawọn fọrọ wa a lẹnu wo, Abdulrahman jẹwọ pe ki i ṣe igba akọkọ ree toun maa ji ẹru ileeṣẹ naa.
Afọlabi ni ẹjọ naa ti wa lẹka to n mojuto eto idajọ nileeṣẹ NSCDC lati gbe igbesẹ to ba yẹ lori ẹ.