Ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe ọda jona ni Kwara, ọpọ dukia lo ṣofo  

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ina sẹ yọ nileesẹ ti wọn ti n pese ọda (Paint Chemical Company) to wa ni opopona ileesẹ Lubcon, nijọba ibilẹ Iwọ Oorun Ilọrin (West), niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, to si ba dukia olowo iyebiye jẹ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ Ọjọruu ni ina ọhun sẹ yọ, ti wọn o si mọ ohun to fa a titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ.

Alukoro lẹka iroyin ileeṣẹ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassan Hakeem Adekunle, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ki ajọ awọn too de ibi ijamba ina naa, nnkan ti bajẹ jinna, sugbọn ni kete tawọn debẹ lawọn pana ọhun to ku patapata. O tẹsiwaju pe awọn eroja kẹmika to wa nileesẹ ọhun lo jẹ ki nnkan bajẹ kọja afẹnu sọ, tori pe o yara ran mọ ina.

O waa parọwa is gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati maa ṣọra ṣe fun gbogbo ohun to le sokunfa ijamba ina, ki wọn si maa ran ara wọn lọwọ lasiko pajawiri.

Leave a Reply