Ileeṣẹ agunbanirọ fiya jẹ mọkanla ninu wọn to n sa lẹnu iṣẹ

 Ọlawale Ajao, Ibadan

 Yatọ si awọn meji to j’Ọlọrun nipe lasiko ti wọn n ṣiṣẹ sin ilẹ baba wọn lọwọ, mọkanla ninu awọn akẹkọọ-jade nileewe giga ti wọn ṣe ìsìnrúùlú wọn nipinlẹ Ọyọ ni ko le ba awọn ẹgbẹ wọn pari eto naa.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn NYSC, iyẹn ajọ to n ṣakoso eto ìsìnrúùlú nilẹ yii, ẹka ipinlẹ Ọyọ, ṣe fagi le iṣẹ ti awọn agunbanirọ ọhun ṣe fun odidi ọdun kan ti wọn lo nibi eto ọhun.

Pẹlu igbesẹ yii, awọn agunbanirọ mọkọọkanla ọhun ko ni i le pada sile koowa wọn lasiko ti awọn yooku wọn ti pari eto ọlọdun kan ọhun, eyi ti wọn ṣe lati fi ṣiṣẹ sin Naijiria ti i ṣe ilẹ baba wọn.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ aṣekagba ìṣí keji, ìsọ̀rí keji awọn agunbanirọ ọdun 2020 yii ti wọn ṣẹṣẹ pari ìsìnrúùlú wọn ni ipinlẹ Ọyọ, Adari ajọ naa, Abilekọ Grace Ogbuogebe, sọ pe niṣe lawọn mọkọọkanla naa maa tun isinruulu wọn ṣe fun odidi ọdun kan. Idi ni pe wọn n sa lẹnu iṣẹ, bẹẹ ni wọn tapa si awọn ofin ati ilana ajọ NYSC mi-in lasiko ti wọn n ṣiṣẹ sin ilẹ baba wọn lọwọ.

Awọn akẹkọọ-jade kaakiri awọn ileewe giga ilẹ yii ti wọn jẹ ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹrun o le meji (2,892) ni wọn kopa ninu eto yii gẹgẹ bi ọga wọn ṣe fidi ẹ mulẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹẹdẹgbẹjọ ati mẹẹẹdọgbọn (1,525) ninu awọn to ṣẹṣẹ sin ilẹ baba wọn tan yii ni wọn jẹ obinrin. Ogoji (40) ninu wọn lo si ṣeto isinruulu wọn nílànà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ninu awọn wọnyi  la ti ri awọn  alaboyun, awọn to bimọ lasiko eto ọlọdọọdun to pọn dandan naa.

O ni eto ọhun ko la ariya lọ lọtẹ yii nitori ajakalẹ arun Korona to wa nita, eyi to n ba gbogbo aye finra.

O waa gba awọn akẹkọọ-gboye naa nimọran lati maa ṣamulo gbogbo ẹkọ iwa ifarada, akinkanju ati iwa ọmọluabi ti wọn kọ lasiko ti wọn fi sin ilẹ baba wọn ọhun.

 

Leave a Reply