Ileeṣẹ Glo fẹbun pataki ta awọn onibaara wọn lọrẹ

 Adefunkẹ Adebiyi

Ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ nni, Globacom, ti kede pe ko din ni onibaara mẹtalenigba (203)  ti wọn yege ninu abala akọkọ tẹtẹ oriire to n lọ lọwọ, eyi ti wọn pe ni ‘Unlimited Extravaganza Promo’.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ yii fi sita lọjọ Ẹti, ti wọn pe akọlẹ ẹ ni ‘ Awọn oloriire fo fayọ bi wọn ṣe n gba agbayanu ẹbun idije alailopin’ ni wọn ti ṣalaye pe oludije mọkanlelaaadọrin ( 71) lo jẹ ẹrọ tẹlifiṣan, awọn mọkanlelaaadọrin mi-in jẹ jẹnẹretọ, nigba tawọn mọkanlelọgọta (61) fi ẹrọ amomitutu ti i ṣe firiiji ṣefa jẹ.

Ẹka ileeṣẹ Glo to wa ni Adeọla Ọdẹku, Victoria Island, l’Ekoo, ni ayẹyẹ ifẹbuntọrẹ naa ti waye.

Lara awọn eeyan pataki lawujọ to gbe ẹbun fawọn onibaara to ṣoriire naa ni Ọgbẹni Ẹniọla Bello ti i ṣe Olootu agba fun iwe iroyin This Day, ati Ọnarebu Desmond Elliot to jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin Eko. Alaga ijọba ibilẹ idagbasoke Eti-Ọsa; Ọgbẹni John Ogundare naa wa nibẹ pẹlu Abilekọ Priscilla Onuzulun ti i ṣe adari ẹka ileeṣẹ to n ri si tẹtẹ tita nipinlẹ Eko, Ajagun-fẹyinti Tunji Shelle atawọn olorin bii King Sunny Ade ati Tẹni D’Entertainer naa ko gbẹyin.

Abilekọ Patience Ozokwor tawọn eeyan mọ si Mama G naa wa nibẹ pẹlu Bọọda Shagi ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Samuel Perry, ati Godwin Komone ( Gordons).

Alakooso ọja tita l’Ekoo nileeṣẹ Globacom, Abdulrazaq Ande, ṣalaye pe ileri tawọn ṣe fawọn onibaara tootọ nileeṣẹ Glo lawọn mu ṣẹ.

O ni ọsẹ mẹta sẹyin ni Glo ṣiṣọ loju eto lati dun awọn ọmọ Naijiria ninu lasiko Keresimesi, titi wọnu ọdun tuntun, apẹẹrẹ rẹ naa ni ẹbun ọlọkan-o-jọkan tawọn eeyan fi ṣefajẹ yii.

 

Leave a Reply