Ileeṣẹ ọlọpaa ṣekilọ fawọn to fẹẹ bẹrẹ iwọde SARS lẹẹkeji l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, ti tun laago ikilọ setiigbọ awọn ọdọ ataraalu pe awọn o ni i faaye gba ohunkohun to jọ iwọde tabi ifẹhonu han nipinlẹ naa, bo ti wu ko kere mọ, tori naa, ki gbogbo ẹni to ba n gbero rẹ tete kuro nidii nnkan bẹẹ.

Alukoro ileeṣẹ naa, SP Olumuyiwa Odumosu, lo fi ikede naa ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde yii, lorukọ ọga rẹ.

Ninu alaye to ṣe, Odumosu ni awọn ti gbọ nipa bawọn eeyan kan ṣe tun bẹrẹ si i mura ija, ti wọn n gba awọn ọdọ kan jọ, ti wọn si tun fẹẹ dana iwọde ti wọn pe ni #EndSARS 2 (Iwọde ta ko SARS keji) nipinlẹ naa. O ni olobo to ta awọn fihan pe ọjọ Aje, Mọnde yii, ni wọn fẹẹ bẹrẹ kinni ọhun lawọn ikorita kan ti wọn ti yan laayo.

Odumosu ni rogbodiyan ati adanu nla ti iwọde ta ko SARS to waye kọja fa fawọn olugbe ipinlẹ Eko ko ti i kuro lọkan ọpọ eeyan, otutu rẹ ṣi n mu wọn, paapaa awọn to padanu mọlẹbi wọn sinu wahala ọhun, tori naa, ko bọgbọn mu fẹnikan lati tun fẹẹ rawọ le iru nnkan bẹẹ.

Latari eyi, o ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i maa woran ki iru iwọde bẹẹ waye, ko tiẹ saaye fun iwọde eyikeyii ni, iba jẹ ti alalaafia tabi omi-in. O fi kun un pe gbogbo awọn agbofinro loriṣiiriṣii lawọn ti dira fun lati wa lojufo, ki wọn si tete tu irufẹ iwọde tabi ikorajọ bẹẹ ka loju-ẹsẹ.

Hakeem tun kilọ fawọn obi lati kiyesi awọn ọmọ wọn, ki wọn ba wọn niwọọ, tori ọmọkọmọ to ba tun daṣa ṣiṣe iwọde kan, tọwọ ba fi le to o, yoo da ara rẹ lẹbi, o si tun rọ gbogbo olugbe Eko lati tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti ti wọn ba kẹẹfin ikorajọ eyikeyii laduugbo wọn.

Leave a Reply