Ileeṣẹ ọlọpaa ṣi ikanni kan fawọn ti wọn ba lu ni jibiti lori ẹrọ ayelujara

Faith Adebọla, Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti ṣi ikanni kan tawọn araalu ti le maa fẹjọ sun ti wọn ba ko sọwọ awọn onijibiti lori ẹrọ ayelujara tabi awọn ti wọn n fi intanẹẹti wọ owo asunwọn banki wọn.

Oju opo ikanni naa ni:  https://incb.police.gov.ng/

Alukoro ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Eko, SP Olumuyiwa Adejọba, lo sọ eleyii di mimọ fawọn akọroyin nigba to n sọrọ nipa ikanni yii lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee yii, pe o maa rọrun fawọn agbofinro lati tete tọpaṣẹ awọn gbaju-ẹ ori atẹ ayelujara, lati wadii wọn, ki wọn si fọwọ ofin mu wọn.

O ni ko si ibi ti afurasi ọdaran kan le sapamọ si tọwọ ofin ko ni i ba a tori ikanni tawọn ṣẹṣẹ ṣe yii n ṣiṣẹ pẹlu awọn ikanni mi-in kari aye ni, yoo si ṣalaye iṣẹlẹ naa fawọn lẹkun-unrẹrẹ fun awọn agbofinro lori ohunkohun ti wọn ba fẹẹ mọ nipa afurasi ti wọn n wa.

Adejọbi ni loju ẹsẹ ti ẹri ba ti wa pe afurasi kan lu ẹnikan ni jibiti ni ikanni naa yoo ti ta ileeṣẹ ọlọpaa ati ọtẹlẹmuyẹ agbaye (Interpol) lolobo, pẹlu awọn olobo to maa jẹ kọwọ tete ba ẹni ti wọn n wa ọhun nibikibi to ba fara pamọ si.

Bo tilẹ jẹ pe olu ilu orileede wa, Abuja ni wọn fidi ikanni naa kalẹ si, wọn ni ẹka rẹ kan wa l’Ekoo, ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Alagbọn, lagbegbe Ikoyi.

Alukoro naa waa rọ awọn araalu lati ma ṣe lo ikanni naa fun ẹsun to ba yatọ si jibiti ori ẹrọ ayelujara, ko baa le ṣee ṣe lati tete gbọ ẹjọ awọn ti wọn mu ẹsun to yẹ wa.

Leave a Reply