Ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n wa Sajẹnti to yinbọn fun afẹsọna ẹ lẹnu n’Ikẹja

Faith Adebọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni ọwọ awọn ko ti i tẹ Sajẹnti ọlọpaa kan, Eze Aiwansoba, ti wọn fẹsun kan pe o fibinu yinbọn mọ afẹsọna ẹ, Joy Eze, lẹnu, tibọn ọhun si ba ẹnu ọmọbinrin naa jẹ yannayanna, kọlọpaa yii to sa lọ lẹyin to ṣisẹ buruku naa tan.

Ninu alaye ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Muyiwa Adejọbi, ṣe fun akọroyin wa lori foonu lọjọ Aje nipa iṣẹlẹ yii, o sọ pe awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣi n fimu finlẹ kaakiri lati mọ ibi ti afurasi ọdaran naa lọọ sapamọ si, ṣugbọn idaniloju wa pe bo ti wu ki ẹgbẹrun saamu rẹ sa to, ọwọ ofin yoo ṣi to o laipẹ.

Muyiwa ni ibọn ọlọpaa ti wọn fura pe Eze yin mọ afẹsọna rẹ naa ṣi wa lọwọ rẹ, bo tilẹ jẹ pe gbogbo ibi ti wọn fura pe o le sa lọ ni wọn ti wa a lọ ti wọn ko ti i ri.

Alukoro fidi ẹ mulẹ pe Joy ti ibọn ba lẹnu naa ṣi wa nileewosan, ṣugbọn ara rẹ ti n ya diẹdiẹ, bo tilẹ jẹ pe ko ti i le fi ẹnu sọrọ pupọ.

Nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, ni iṣẹlẹ buruku ọhun waye ni ibudokọ Salvation to wa loju ọna Ọpẹbi, lagbegbe Ikẹja, nipinlẹ Eko. Ile kan to wa ni Opopona Owonikoko, laduugbo Idiagbọn, ni Ọgba, ni Joy n gbe, o si ti to oṣu meloo kan sẹyin toun ati Sajẹnti Eze yii ti n fẹra wọn. Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Special Protection Unit, Base 16, to wa n’Ikẹja, ni Sajẹnti yii ti n ṣiṣẹ.

Afẹsọna rẹ yii ni wọn lo waa ba ọlọpaa ọhun lọfiisi rẹ lọjọ naa, ti ọrọ kan si ṣe bii ọrọ laarin wọn, ṣugbọn wọn ko ri ọrọ naa yanju. Wọn ni Joy lo sọ fun ọlọpaa naa pe oun ko fẹ ẹ mọ to ba ri bẹẹ, kawọn kuku pin gaari.

Ẹnu ọrọ yii ni wọn wa ti Sajẹnti Eze fi sin afẹsọna rẹ yii de bọsitọọpu to ti maa wọkọ pada sile, ṣugbọn bi ariyanjiyan wọn ṣe n gbona si i, ojiji ni wọn lọlọpaa naa tawọ si adọdọ ibọn to gbe dani, lo ba yin in mọ ọmọbinrin naa lẹnu.

Niṣe ni ẹjẹ rẹpẹtẹ wẹ ọmọbinrin ọhun loju ẹsẹ, kawọn eeyan to ti kọkọ sa ṣẹyin nigba ti wọn gburoo ibọn to o tun sa pada de, Sajẹnti Eze ti sa lọ. Awọn ni wọn sare ke si awọn ọlọpaa to wa nitosi, tawọn yẹn si gbe e lọ sọsibitu ijọba to wa n’Ikẹja.

Latigba naa ni ko ti sẹni to gburoo oṣika tan tẹsẹ mọrin ọlọpaa yii, ṣugbọn bi Muyiwa ṣe sọ, o ni ago lo si maa de adiyẹ rẹ gbẹyin.

Leave a Reply