Ileeṣẹ ọlọpaa doola ẹmi arinrin-ajo mẹrin ninu mẹfa tawọn ajinigbe ji gbe ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti kede pe awọn ti doola ẹmi arinrin-ajo mẹrin ninu awọn mẹfa ti awọn ajinigbe ji gbe l’Opopona Obbo-Ile si Osi, nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa, Ọkasanmi Ajayi, fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ti sọ pe mẹrin ninu awọn mẹfa arinrin-ajo ti awọn ajinigbe ji gbe ninu bọọsi akero kan to ni nọmba: Abuja KUJ 613 AA laaarin Obbo-Ile, si Osi, leyii ti awọn ajinigbe marun-un ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro miiran jigbe. O tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa ati ẹgbẹ fijilante ti wọnu igbo ni agbegbe naa lati doola awọn meji to ku lakata awọn ajinigbe. O fi kun un pe wọn ti ri ọkọ awọn afurasi naa ti wọn ko ounjẹ sinu ẹ bamu-bamu pẹlu awọn ohun ija oloro.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Tuesday Assayomo psc (+), fi da mọlẹbi awọn to ku lakata ajinigbe loju pe laipẹ lawọn yoo doola awọn eeyan wọn, bakan naa lo gba olugbe ipinlẹ Kwara, nimọran pe ki wọn yẹra fun irin-ajo alẹ.

Leave a Reply