Ileewe ti Adebọla ti n ṣe agunbanirọ lo ti fipa ba ọmọọlọmọ lo pọ

Faith Adebọla, Ogun

Bi wọn ba n powe ‘ekurọ lo waa ra lọja, ọmọ ẹran ti ṣe de’gba,’ afurasi ọdaran kan ti wọn porukọ ẹ ni Sodiq Adebọla yii gan-an lowe ọhun ba mu rẹgi, iṣẹ aṣesinsinlu ọlọdun kan tijọba maa n yan awọn agunbanirọ si, iyẹn awọn ti wọn ba ti pari iwe tan ni fasiti tabi poli, lọkunrin naa n ṣe lọwọ nileewe kan l’Owode-Ẹgba nipinlẹ Ogun, amọ niṣe lo lọọ fẹtan mu ọmọbinrin ẹni ogun ọdun kan wọ yara ẹ, lo ba fi tulaasi ba a laṣepọ, igbadun iṣẹju diẹ ohun si ti sọ ọ dero ahamọ ọlọpaa, o ti n ṣẹju peu bii ẹyẹ to waya ọlọdẹ, lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ bayii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, lo taṣiiri ọrọ yii fawọn oniroyin ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Wasaapu rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un ta a wa yii.

Alukoro naa ṣalaye pe lọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un yii, iyẹn ọjọ Tusidee to kọja, Agunbanirọ yii lọọ silegbee awọn obinrin ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ kan lagbegbe Owode-Ẹgba naa, wọn lo ti n yan ọkan lara awọn ọdọmọbinrin naa lọrẹẹ tẹlẹ, oun ati onitọhun jọ n ṣe bọifurẹndi ati gẹifurẹndi, ọrẹbinrin ẹ yii si ni ọrẹ kan toun atiẹ jọ n gbenu yara.

Lọjọ iṣẹlẹ ọhun, Sọdiq wa ọrẹbinrin ẹ lọ amọ ko ba a nile, ọrẹ ẹ lo ba, lo ba ni ki ọmọbinrin ẹni ogun ọdun ti wọn forukọ bo laṣiiri naa sin oun jade, oun fẹẹ ra awọn ẹbun oriṣiiriṣii fun ti ayẹyẹ ọrẹbinrin oun, ti i ṣe ọrẹ tiẹ naa, to n bọ lọna, obinrin yoo si kuku mọ nnkan to daa lati ra fobinrin ẹgbẹ ẹ, niyẹn ba gba lati sin in lọ sọja ti wọn ti n ta awọn ẹbun, lai fura pe ologbo to sun bii ọlẹ l’Agunbanirọ yii, ọgbọn inu ẹ pe egbeje.

Wọn ni bi wọn ṣe n lọ lọna, lafurasi ọdaran yii ba poṣe lẹẹkan naa pe oun ti gbagbe wọlẹẹti (wallet) oun sile, iyẹn apo ikowosi tabi pọọsi tawọn ọkunrin maa n lo, o ni ki ọrẹ ọrẹbinrin ẹ yii jọọ sin oun dele koun sare mu un, kawọn si tete ra nnkan tawọn fẹẹ ra ọhun.

Ọmọbinrin yii sọ fawọn ọlọpaa pe tori oun jẹ ọrẹ ọrẹbinrin ẹ, ti Agunbanirọ yii si mọ oun daadaa lo jẹ koun fọkan tan an pe ko jẹ ṣere egele kankan pẹlu oun, afi boun ṣe si in debi tawọn Kọpa maa n gbe, lo ba ki oun mọlẹ, lo ni dandan ni koun ba oun laṣepọ, ere loun kọkọ pe e, nigba to si ya, oun bẹrẹ si i bẹ ẹ, boun ṣe n bẹ ẹ loun n sunkun yọbọ, amọ oju jagunlabi ti ranko, afigba to ṣe ‘totomẹlẹto’ ọran-an-yan pẹlu oun lo too fi oun silẹ, lo waa ni koun ma binu.

Ọmọbinrin yii lo gba teṣan ọlọpaa lọ lẹyin iṣẹlẹ ọjọ naa, to lọọ fẹjọ Kọpa Adebọla Sọdiq sun, lawọn agbofinro ba fi dọdẹ ẹ, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e.

Ni teṣan, nigba ti wọn beere bọrọ ṣe jẹ lọwọ afurasi yii, ko jampata rara o, ọwọ kan lo ti jẹwọ pe loootọ loun huwa abeṣe naa, amọ o ni ki wọn ṣaaanu oun, o loun o tiẹ mọ nnkan to rọ lu oun lọjọ naa toun fi da iru nnkan bẹẹ laṣa, o ni ki wọn fori ji oun.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Ọlanrewaju Ọladimeji ti gbọ siṣẹlẹ yii, o si ti paṣẹ ki wọn taari Agunbanirọ oniṣekuṣe yii sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣewadii ijinlẹ nipa iru awọn iwa ọdaran bii eyi lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleleweẹran, l’Abẹokuta.

Ibẹ ni wọn ni Kọpa yii yoo gba dewaju adajọ laipẹ, ki wọn le sọ itumọ iwa rẹ fun labẹ ofin.

Leave a Reply