Ilu Arigidi la fẹ ki wọn sin TB Joshua si – Ọba Yisa Ọlanipẹkun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Zaki ilu Arigi Akoko, Ọba Yisa Ọlanipẹkun, ni awọn ilu ti ranṣẹ ikilọ sawọn ọmọ ijọ Sinagọgu lati ri i daju pe wọn tọju oku Pasitọ Temitọpẹ Balogun Joshua to ku lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja daadaa, nitori pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ṣewadii iku to pa gbajugbaja iranṣẹ Ọlọrun naa.

Ọba Ọlanipẹkun sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi ransẹ sawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ọsẹ yii.

O ni oun rọ awọn ọmọ ijọ olusọaguntan naa lati mojuto oku rẹ daadaa titi di igba ti awọn yoo fi mọ ohun to ṣokunfa iku ẹni wọn ọhun.

Zaki ni ireti awọn eeyan ilu Arigi ni pe ki wọn ṣeto ati gbe oku olori ijọ Sinagọgu naa wa siluu abinibi rẹ waa sin, nitori pe eyi ni ko ni i jẹ ki awọn ipa rere to ti fi lelẹ ṣee gbagbe laelae.

O ni bi wọn ba le gbe oku Wolii Mose Orimọlade to jẹ oludasilẹ ijọ Kerubu ati Serafu kaakiri agbaye wa siluu Ikarẹ Akoko lati waa sin, ko si idi ti ko fi yẹ kí wọn gbe T. B. Joshua naa wa siluu rẹ ki wọn le ṣẹyẹ ikẹyin fun un.

Gbogbo ọja, ile-itaja ati ṣọọbu to wa niluu Arigidi ati agbegbe rẹ ni wọn ti pa lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lati bu ọla ikẹyin fun oloogbe ọhun, bẹẹ lawọn eeyan n rọ kẹtikẹti lọ sile ẹbi rẹ to wa niluu ọhun lati ba ẹgbọn rẹ to ku nile, Ọgbẹni Abimbọla Balogun kẹdun.

Lati aarọ ọjọ Aiku, Sannde, si ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii, ti wọn tufọ iku Joshua, o ti le lọọọdunrun-un awọn eeyan ti wọn ti fọwọ si iwe ibanikẹdun ti wọn si siwaju ile ẹbi wọn to wa l’Arigidi Akoko.

Ọrọ kan ṣoṣo ti ẹgbọn rẹ si n tẹnumọ ni pe ọfọ ayeraye lo ṣẹ awọn, o ni ko si bi awọn ẹbi ati araalu ṣe fẹẹ gbagbe rẹ latari ipa ribiribi to ti ko ninu igbe aye wọn.

Lara awọn to ba awọn ẹbi T. B. Joshua kẹdun ni Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Onigedegde ti Igedegede, Ọba Walidu Sanni, Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, Alagba Ayọdele Akande, Alaaji Ibrahim Kilani to jẹ ọkan pataki lara awọn olori ẹlẹsin Musulumi lagbegbe Akoko.

Leave a Reply