Monisọla Saka
Ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilu Eko kan ti ṣeleri pe awọn ko ni i fara mọ ofin to fẹẹ da ijọba Naijiria pada si ẹlẹkunjẹkun.
Awọn ẹgbẹ ti wọn n jẹ De Renaissance Patriots Foundation, ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn ti sọ pe ofin tuntun ti wọn fẹẹ gbe jade yii, nibi ti ileegbimọ aṣofin ilẹ wa ti fẹẹ da eto iṣejọba ilẹ Naijiria pada si ẹlẹkunjẹkun ti wọn n lo tẹlẹ ko ni i le jẹ itẹwọgba fawọn nipinlẹ Eko, nitori awọn ko ni i le dara pọ mọ ẹkun Iwọ Oorun ilẹ wa (Western Region).
Ninu atẹjade ti Adelani Adeniji-Adele, to jẹ akọwe iroyin wọn fi sita, lo ti ni, “Abadofin ti wọn n gbe kiri yii jẹ apẹẹrẹ buburu fun wa nipinlẹ Eko. Ọna lati tubọ tẹ wa ri gẹgẹ bii ẹya nla kan ni a ri i si.
Ohun to jẹ akọkọ, to si ṣe pataki ju, ni pe wọn ko ṣe ifiwẹlọ tabi ifọrọjomitoro ọrọ kankan lori ọrọ yii lati mọ boya ki wọn jan wa pọ mọ awọn ẹkun agbegbe kan jẹ ohun ta a fẹ. Ẹ o kan le wo o pe o yẹ bẹẹ lati apa ọdọ yin.
“Latigba ti ipinlẹ Eko funra ẹ ti wa lo ti maa n wu wa ka da wa gedegbe, yatọ si wiwa labẹ ẹkun Iwọ Oorun tabi agbegbe ibi kan.
“A ranti pe ninu itan ilẹ wa lati bii ọgọrun-un ọdun o le sẹyin. Awọn ọmọ Eko kaakiri, niluu atawọn igberiko ko ti i ni itẹsiwaju kan gẹgẹ bii ọkan lara agbegbe kan, ka ma ti i waa sọ ti ẹkun Iwọ Oorun. Ọna lati dabaru eto wa, ati iduro wa bii ilu kan ni bi wọn ṣe fẹẹ jan wa pọ mọ apa Iwọ Oorun.
“Ki wọn ma ro ohunkohun lori ọrọ abadofin yii, agaga to ba ti jẹ pe wọn fẹẹ fi ipinlẹ Eko sinu ẹkun agbegbe kan. Ero awọn eeyan ni a fẹ ko ṣẹ.
Awa ẹgbẹ ọmọ bibi ipinlẹ Eko ko fẹ lati dara pọ mọ ijọba agbegbe kankan gẹgẹ bi wọn ṣe fẹẹ da ijọba Naijiria pada si ti atijọ. Awọn olori wa atawọn ọba alaye wa ta ko o lọdun 1953, wọn si fi wa lọrun silẹ ni ọdun 1967. Awa ta a jẹ ọmọ fawọn akinkanju eeyan to ti lọ yii ko ni i tẹwọ gba a.
“A n rọ awọn aṣoju wa nileegbimọ aṣofin lati ba awọn agbaagba ọmọ Eko atawọn eekan laarin ilu jiroro ki wọn too gbe igbesẹ kankan lori ofin tuntun naa. Eleyii kọja ti ẹgbẹ oṣelu to wa nipo tabi ti ijọba ipinlẹ. Wọn ko le waa sọ ipinlẹ Eko di ohun ti ko ja mọ nnkan kan latari bi wọn ṣe fẹẹ da a pọ mọ ẹkun Iwọ Oorun ti wọn n gbero ẹ. Ariwo tawọn baba nla wa pa lasiko ijọba amunisin ko yipada o”.
Bayii ni wọn sọ ọ sinu atẹjade ti wọn fi sita ọhun.