Isẹyin lọwọ ti tẹ Abubakar, ọkan lara awọn to sa l’ọgba ẹwọn Abolongo, l’Ọyọọ

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ọkan lara awọn meji ti wọn sa lọgba ẹwọn lasiko tawọn afurasi janduku agbebọn kan lọọ ṣakọlu sọgba ẹwọn Abolongo, niluu Ọyọ, ipinlẹ Ọyọ, loṣu to kọja. Agbegbe ilu Isẹyin lọwọ ti ba ọkunrin naa.

Lara wọn ni Mohammed Abubakar ati ekeji rẹ, Aliu Haruna, ṣugbọn Haruna tun raaye sa lọ, awọn agbofinro si ṣeleri pe o di dandan kawọn ṣawari rẹ.

Deedee aago marun-un idaji ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni olobo ta awọn ọlọpaa pe awọn eeyan meji kan n rin gberegbere ni abule ti wọn n pe ni Ibudo Laagbe, ni aba Serafu, loju ọna to lọ siluu Ibadan lati Isẹyin, wọn lawọn ọkunrin naa ṣẹṣẹ de saduugbo ọhun ni, irin wọn si mu ifura lọwọ.

Ninu alaye ti Olori awọn Fulani lagbegbe Oke-Ogun, Oloye Baani Abubakar, ṣe fun akọroyin wa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, lo ti sọ pe gbara ti wọn ṣakọlu sọgba ẹwọn naa ni Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, ti gbe awọn akanṣe iṣẹ kan le awọn lọwọ. Lara iṣẹ naa ni lati ṣawari awọn to sa kuro lọgba ẹwọn ọhun, ki wọn si tun ṣiṣẹ oju lalakan fi n ṣọri lori eto aabo agbegbe naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni lati akoko naa lawọn ti yan awọn fijilante Fulani si tibu-tooro gbogbo agbegbe naa, eyi to pada waa seso rere pẹlu ifowọsowọpọ Baalẹ Aba Serafu, Oloye Taiwo Ẹfọ, ẹni to ṣiṣẹ takun takun tọwọ fi tẹ awọn afurasi naa.

O ni gbara ti wọn ti sa lọgba ẹwọn ni wọn ti fọnka sagbegbe naa lati le maa ba iṣẹ laabi wọn lọ, ki wọn too ko sakolo pada yii.

Abubakar ni awọn ti fa wọn le ọlọpaa agbegbe Isẹyin lọwọ, awon agbofinro si ti n ṣeto bi wọn ṣe maa da a pada sẹwọn to ti kuro, bẹẹ ni wọn n wa awọn to ku.

Leave a Reply