Ilu kan ree ti wọn ko gbọdọ rẹrin-in fun ọjọ mọkanla gbako

Ki i ṣe pe o dun mọ awọn araalu lati di ẹnu wọn pa fọjọ mọkanla lai rẹrin-in, idunnu wọn kọ ni pe wọn ko gbọdọ mu ọti tabi fi ayọ kankan han fọjọ mọkanla gbako, awọn alaṣẹ ilu lo fipa mu wọn bẹẹ, wọn ni bẹẹ lo gbọdọ ri lati ṣe iranti ati ibanikẹdun ọdun kọkanla ti aarẹ wọn tẹlẹ, Kim Jong-il, jade laye. Njẹ kin ni orukọ orilẹ-ede ti aṣẹ yii ti n waye? North Korea ni.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila yii, lo pe ọdun mọkanla ti Kim Jong-il jade laye. Apaṣẹ-waa ni wọn pe e, ijọba onikumọ si ni ijọba rẹ to bẹre lọdun 1994, to si pari ni 2011, iyẹn lẹyin ti aisan ọkan kọ lu u, ti ọkan rẹ daṣẹ silẹ lẹni ọdun mọkandinlaaadọrin (69).

Lati ọdun 2011 ti ọkunrin naa ti jade laye ni wọn ti ya ayajọ ọjọ iku rẹ sọtọ, pe ẹnikẹni ko gbọdọ rẹrin-in, ko gbọdọ si pe eeyan n ṣe ajọyọ ọlọti, koda, bi ọjọ ibi araalu kan ba bọ si asiko ti wọn ya sọtọ fun iranti iku Kim, tọhun ko gbọdọ ṣe e, afi lẹyin ọjọ mẹwaa ti iranti olori naa ba lọ tan.

Lọdọọdun, ọjọ mẹwaa ni wọn fi n ṣe iranti ati ikẹdun Kim Jong-il, ṣugbọn lọdun 2021 yii to pe ọdun mẹwaa ti alaṣẹ wọn naa ku, wọn fi ọjọ kan kun ọjọ ikẹdun, iyẹn lo fi jẹ ọjọ mọkanla ni ko fi ni i si idunnu lọkan awọn araalu, to jẹ ibi gbogbo gbọdọ kan gogo ti yoo fi pe ni.

“Ko si ẹni ti wọn bi daa ti yoo tapa sofin yii, ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o n rẹrin-in nibikibi, idajọ ọdaran taara ni wọn maa n da fun wọn. Ti wọn ba fi le mu tọhun lọ bayii, ko ni i wale mọ, ẹnikẹni ko ni i foju kan an mọ laye yii, o di gbere niyẹn.” Bẹẹ ni ọmọ Kọrea kan lati ilu Sinuijum, ṣalaye fun ileeṣẹ Redio Free Asia ( RFA).

Boya ofin onikumọ yii ko ba ma rẹsẹ tilẹ bi ki i baa ṣe pe ọmọ Kim lo tun di olori awọn eeyan yii lẹyin iku baba rẹ. Ọmọ kẹta ti oloogbe naa bi to jẹ ọkunrin, Kim Jong Un, lo ti n dari wọn bọ pẹlu aṣẹ buruku yii lati ọdun 2011 ti baba rẹ ti ku, bo ba si ti sọrọ bayii, aṣẹ gun un ni.

Wọn ti bẹrẹ aigbọdọ fẹyin, muti tabi fi idunnu han ti ọdun yii lati ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ki wọn si too bọ ninu ẹ di ẹyin Keresimesi, iyẹn ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila ọdun 2021.

Leave a Reply