Imaamu Yoruba n’Ilọrin ni: Ẹṣin o faja, awọn aafaa o lẹtọọ lati di Yeye Ọṣun lọwọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ohun to kọju sẹni kan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran bii ilu gangan, lọrọ awuyewuye to n waye niluu Ilọrin lori ayẹyẹ ajọdun ti Yeye Ajeṣikẹmi Ọmọlara fẹẹ ṣe tawọn aafaa kan niluu Ilọrin ta ko. Imaamu agba Yoruba niluu Ilọrin, Abdul Raheem Aduanigba, ti sọrọ lori igbe sẹ naa, o ni awọn aafaa ko lẹtọ lati di Yeye Ọṣun lọwọ tori pe ẹṣin ko faja.

Ninu ọrọ ti baba naa ba ALAROYE sọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Keje yii, ni aafin rẹ to wa ladojukọ Ileewosan Eyitayọ, lopopona Ọja-Ìyá, niluu Ilọrin, lo ti bẹnu atẹ lu bi awọn aafaa Ilọrin ṣe lọọ n dunkooko mọ Yeye Ọṣun Ajesikẹmi Ọmọlara, pe ko gbọdọ ṣe ọdun Ọṣun to n gbero pe oun fẹ ṣe to ba nifẹẹ ara rẹ ati awọn ọmọ rẹ. Imaamu Yoruba ni orile-ede Naijiria ki i ṣe orile-ede ti wọn ti n sin ẹṣin ẹyọ kan. O ni Saudi, tabi orileede Iran, ni wọn ti yan ẹṣin Isilaamu nikan laaayo, sugbọn ni Naijiria, ẹsin mẹta ni a ni, ẹsin Igbagbọ ti awọn ọmọlẹyin Kirisiti, ẹṣin Isilaamu ati ẹṣin ibilẹ, paapaa ju lọ nipinlẹ Kwara, ẹlẹsin kan ko si gbọdọ di ikeji lọwọ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni onikaluku lo ni ẹtọ labẹ ofin Naijiria lati sin ẹṣin to wu hu u lorilẹ-ede yii lai si idiwọ Kankan. Ki Musulumi fọla Anọbi tọrọ, kawọn ọmọ lẹyin Kirisiti ba Jesu sọrọ, kawọn oniṣẹṣẹ bẹ Ifa olokun lọwẹ, ki alaafia le jọba.

O tẹsiwaju pe niluu Ilọrin la ti n ri awọn ọrọ bii Ọba òrìṣà ipinlẹ Kwara, Ọba iṣẹṣe ipinlẹ Kwara, Olori iṣẹṣe Kwara ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti ko si sẹni to ta ko o, ṣugbọn ti wọn ba fẹẹ sọdun wọn ni awọn aafaa yoo ta ko wọn, ti awọn Yoruba to n gbe ni awọn ipinlẹ Ọṣun, Ekiti, Ondo, nibi ti awọn ẹlẹsin Igbagbọ pọ si naa ba ta ku pe awọn Musulumi ko gbọdọ sọdun Ileya tabi kirun jimọ, ṣe wahala ija ẹṣin ko ni i waye? O ni ki awọn aafaa to n ta ko awọn ẹlẹsin ibilẹ lọọ tun ero wọn pa, ki wọn si tẹle ọrọ Ọlọhun to ni “Quliyahayua Alkafiruna” ki Musulumi maa ṣin ẹṣin wọn, kawọn ti ki i ṣe Musulumi naa ṣe tiwọn lọtọ, ki wọn maa di ara wọn lọwọ.

Fun idi eyi awọn aafaa ko lẹtọ lati ta ko awọn oniṣẹṣe niluu Ilọrin, tori pe ẹṣin ko faja.

O rọ awọn aafaa ki wọn gba alaafia laaye, ki wọn ma da ija ẹṣin silẹ, o ni ẹṣin ko faja, ati pe ọmọ iya kan naa ni ẹlẹsin mẹtẹẹta.

Imaamu ni ki wọn lọọ mojuto awọn ajinigbe to n ji awọn ọmọ Naijiria gbe lawọn oju ọna marosẹ, ati pe ti awọn oniṣẹṣe ba gbe awọn aafaa lọ sile-ẹjọ lori ọrọ yii, awọn aafaa yoo yẹyẹ ara wọn nile-ẹjọ ni.

Leave a Reply