Imu arufin la maa mu ọlọkada to ba gba ọna ti ko tọ, tabi ẹnikẹni to ba ba dukia ijọba jẹ- Sanwo-olu

Aderohunmu Kazeem

Gomina Babajide-Sanwo-Olu, ti sọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ to gun ọkada loju popo tijọba Eko fofin de, tabi ba dukia ijọba jẹ, yoo daran ofin, bẹẹ ni ijiya buruku ni yoo si tẹle e pẹlu.

O ni o jẹ ohun to ba ni ninu jẹ pe pupọ ninu awọn to n gun ọkada kiri loju popo l’Ekoo, paapaa lawọn aaye tijọba ti sọ pe wọn ko gbọdọ gba ni wọn ko le ṣe bẹẹ nipinlẹ ti wọn ti wa gan-an.

Gomina ni ohun ti oun mọ ni pe pupọ ninu awọn eeyan ti wọn fẹẹ fi ọkada ba ilu Eko ti gbogbo aye n foju ilu nla wo bayii jẹ ni wọn ko le ṣe iru ẹ ni awọn ipinlẹ ti wọn ti wa.

O tẹ siwaju pe iru awọn eeyan yẹn ni wọn n fẹhonu han kiri Eko bayii, ti wọn n ṣe ohun to wu wọn nitori ti ijọba Eko ti faaye gba tẹru-tọmọ. Sanwo-Olu sọ pe wahala koronafairọọsi to da gbogbo agbaye laamu, tijọba paapaa si n sare kiri lati koju ẹ, lo kọkọ fun awọn ọlọkada laaye, ti wọn n gba gbogbo ibi ti ko yẹ ki wọn ti gun ọkada wọn, ati pe nigba ti wahala rogbodiyan SARS naa tun pẹlu ni wọn ti ro pe awọn ti jọba loju popo, ko si ohun tẹnikan le fi awọn ṣe.

Bakan naa lo fi kun un pe nisinyii ti ko si iru wahala bẹẹ mọ, ti ijọba n ṣeto bi ohun gbogbo yoo ṣe bọ sipo ni iwa ̀ọdaran wiwa ọkada lawọn ibi ti ko ti yẹ yẹn ti waa mọ awọn ọlọkada lara.

O ni o ti wọ wọn lẹwu debii pe wọn ko fẹẹ kuro lojupopo mọ, ti wọn si laya lati maa koju ija sawọn agbofinro ijọba to n da wọn lọwọ kọ.

Gomina yii ti waa sọ pe ijọba Eko ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ lati asiko yii lọ, ati pe ki i ṣe awọn ọlọkada nikan o,  gbogbo eeyan to ba ti lọwọ si biba dukia ijọba jẹ ni yoo rugi oyin tọwọ ba tẹ iru wọn.

Bẹẹ gẹgẹ lo fi kun un pe ijọba ko ni i faaye gba iru iwa afojudi to ṣẹlẹ lagbegbe Amuwo-Ọdọfin ati Ikẹja, nibi tawọn ọlọkada ti doju ija kọ awọn ẹṣọ agbofinro nitori ti wọn ni ki wọn ma gun ọkada loju popo mọ. Ati pe ẹni ti ọwọ ba tẹ, ijiya to le ni ijọba yoo fi jẹ ẹ, ti wọn yoo tun gbe e sinu iwe iroyin lati fi kọ ara yooku lọgbọn.

Leave a Reply