Ina ṣẹ yọ nileefowopamọ FCMB, n’llọrin, ọpọ dukia lo jona 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ni nnkan bii aago mẹta kọja ogun iṣẹju Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ina ṣẹ yọ nileefowopamọ First City Monument Bank (FCMB), to wa ni Opopona Murtala Mohammed, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, to si ba dukia olowo iyebiye jẹ.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ni nnkan bii aago mẹta ọsan kọja ogun iṣẹju ni wọn ri i pe eefin n ru, ko pẹ ni wọn ri i ti ina n yọ lala, ti awọn oṣiṣẹ ileefowo pamọ ọhun atawọn onibaara to wa nibẹ si n sa asala fun ẹmi wọn. Nigba ti aago mẹta aabọ ku iṣẹju meji nileeṣẹ panapana de sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn o jẹ ki nnkan bajẹ kọja aala. Awọn oṣiṣẹ ileefowopamọ naa da’ṣẹ duro fun ti ọjọ naa, wọn si bẹ awọn onibaara pe ki wọn pada wa ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, fun eyikeyii ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe. Sugbọn wọn ni ọpọ dukia lo ba iṣẹlẹ naa rin.

 

Leave a Reply