Florence Babạsọla, Oṣogbo
Ọkẹ aimọye miliọnu Naira ni dukia to ṣofo ninu ijamba ina to ṣẹlẹ ninu ọja leku-lẹja, to wa ni Ọja-Ọba, loju-ọna Ibokun, niluu Oṣogbo, nidaaji ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, ọdun.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago kan oru ni ina ti ẹnikẹni ko mọ nnkan to ṣokunfa rẹ titi di asiko ti a n kọ iroyin yii bẹrẹ, o si ti jo bii wakati meji aabọ ki awọn eeyan too mọ.
Ninu ọrọ Alukoro ajọ panapana nipinlẹ Ọṣun, Adekunle Ibraheem, o ni aago mẹrin idaji ku iṣẹju mẹjọ ni ọkunrin kan, Oyedele Muftau, fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ awọn leti.
O ni ko si ju iṣẹju marun-un lọ ti awọn fi debẹ, ti awọn si bẹrẹ si i pana naa, ṣugbọn nnkan ti bajẹ jinna ṣaaju asiko ọhun, odidi ṣọọbu mẹsan-an lo si jo.
Gẹgẹ bi ọkunrin kan to ni ṣọọbu nibẹ, Ọgbẹni Iṣọla Ọlalekan, ṣe ṣalaye fun akọroyin wa, o ni oun ko le sọ ni pato iye owo ọja ti oun padanu sinu ijamba ina ọhun.
O ni awọn oyinbo ilẹ Brazil ni wọn pọ ju ninu awọn ti oun maa n taja fun, awọn iṣẹ kan si wa ti oun ṣe silẹ to jẹ pe ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira loun n ta ẹyọ kan, ti oun si ni mejila ninu ṣọọbu.
O ni oniruuru awọ (leather) loun ṣe silẹ, bẹẹ ni awọn ọja olowo iyebiye wa ninu ṣọọbu oun lasiko tijamba ina ṣẹlẹ yii.
Bakan naa ni obinrin oniṣowo kan nibẹ, Kudirat Ganiyu, sọ pe awọn ko le sọ pato ohun to fa iṣẹlẹ naa. O ni awọn ba awọn panapana nibẹ laago mẹta idaji ti oun debẹ ni. O ni awọn nnkan to bajẹ nibẹ to miliọnu lọna ọgọrun Naira.
Kudirat fi kun ọrọ rẹ pe yatọ si bi awọn ara agbegbe naa ṣe dide lati ba awọn pa ina yii, odidi ọkọ panapana meji ni wọn wa, o si to aago mẹfa aarọ ki wọn too lọ.