Ina gaasi jo ọmọ ọwọ atawọn agbalagba mẹfa pa l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Nigba tawọn eeyan n palẹmọ ọdun Itunu aawẹ to wa nita yii lọwọ, igbe ẹkun lo gbalẹ kan ninu ile kan ti ina gaasi ti bu gbamu lojiji, l’Oke-Igbore, lọna NTA, l’Abẹokuta, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu karun-un yii. Ọmọ ọwọ atawọn agbalagba marun-un  ni ina jo pa lọsan-an gangan.

Ohun ti a gbọ ni pe ọkunrin kan to n tun firiiji ṣe lo n fẹ afẹfẹ gaasi si firiji to n ba wọn tun ṣe lọwọ, asiko to n ṣiṣẹ naa lọwọ ni obinrin kan n din ẹja ninu ṣọọbu kan nitosi ibẹ.

Ina ti obinrin naa n da lo ran gaasi ti oniṣẹ-ọwọ n fa lati inu silinda lọwọ, bi ina ṣe sọ lojiji ninu ile niyẹn, to si mu ọkunrin to n ṣe firiji naa ati obinrin to ni ṣọọbu to ti n ṣe e, pẹlu ọmọ ọwọ to wa nibẹ naa. Gbogbo wọn jona ku ni.

Awọn aladuugbo to wa nitosi sọ pe yatọ sawọn mẹta to jona mọle yii, awọn eeyan mẹta mi-in naa tun fara ko ina yii pupọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ku lẹsẹkẹsẹ bii awọn mẹta akọkọ.

Wọn ni ọlọkada to gbe ọkunrin to n ṣe firiiji naa wa sibẹ paapaa fara ko ina, oun naa si wa ninu awọn meji yooku to pada ku ki wọn too gbe wọn de ileewosan.

Ṣugbọn ọga awọn panapana nipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Fatai Adefala, sọ pe eeyan mẹta lo ku ninu iṣẹlẹ yii, nigba ti ko si ọna abayọ fun wọn.

O ni bo tilẹ jẹ pe awọn lọ sibẹ lati pana ọhun nigba tawọn gba ipe lati ile naa, o ni ko sohun ti ẹnikẹni le ṣe si i lo fa a tawọn mẹta naa fi jona ku.

Adefala sọ pe awọn to pe awọn ko tilẹ sọ pe gaasi lo gbina, wọn kan ni ina kan ara wọn ni, igba tawọn debẹ lo di ina nla to ti ṣọṣẹ gidi.

Nnkan bii aago mẹta ọsan kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ni Adefala sọ pe awọn gba ipe naa, titi digba ta a si fi pari iroyin yii, awọn oṣiṣẹ panapana atawọn ẹṣọ alaabo ṣi wa nibẹ, ti wọn n ṣeto bi wọn yoo ṣe palẹ awọn to doloogbe naa mọ.

Leave a Reply