Ina jo eeyan mẹsan-an pa l’Owode-Idiroko, tanka epo lo gbina

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun aarọ ni ijamba ina kan ṣẹlẹ lagbegbe Ajilete, l’Owode-Idiroko, nipinlẹ Ogun, l’Ọjọruu, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 2021, ko si din leeyan mẹsan-an to doloogbe nibi iṣẹlẹ naa.

Awọn tiṣẹlẹ aburu naa ṣoju wọn ṣalaye pe tanka epo kan lo fẹẹ sọkalẹ lapa ibi kan to ṣe gẹrẹgẹrẹ, nigba naa ni apa ibi ti epo wa deede yọ kuro lara tanka agbepo yii, bo ti ja bọ silẹ lo n yi gbiiri, bẹẹ lo pariwo gbau, ni ina nla ba ṣẹ yọ.

Lita ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn (33,000) ni tanka epo naa gbe, bi ina ṣe ṣẹ yọ lo bẹrẹ si i jo pẹlu agbara. Ẹsẹkẹsẹ leeyan marun-un ti jona ku, awọn mẹrin mi-in tina ọhun fọwọ ba naa si ku tẹle e, bẹẹ lawọn meji fara pa.

Kọmanda TRACE l’Oke-Ọdan, Akintoye A.M, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni ọkada ati mọto kan naa fara gba ina yii, wọn jona raurau.

Akintoye sọ pe ki i ṣe pe mọto kan rọ lu tanka agbepo yii bawọn kan ṣe n wi, o ni ori rẹ lo yọ kuro lara rẹ, ohun to fa ijamba niyẹn.

Ọkunrin ni gbogbo awọn mẹsan-an to jona ku yii.

Leave a Reply