Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ileesẹ to n ri ṣeto ẹkọ kari aye nipinlẹ Ondo (SUBEB) lo ti jona patapata latari ina ojiji kan to deedee ṣẹ yọ nibẹ loru ọjọ Aiku, Sannde, mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.
Lara awọn ile to tun fara gba ninu ijamba ina ta a n sọrọ rẹ yii ni gbogbo ọfiisi ipolowo ọja to jẹ ti ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan ipinlẹ Ondo (OSRC) to wa ninu ọgba Oke-Ẹda, niluu Akurẹ.
Ninu alaye ti ọkan ninu awọn ẹsọ alaabo to wa nitosi lasiko tiṣẹlẹ naa waye ṣe fun wa, o ni ni nnkan bii aago mejila oru ni ina ajeji yii ṣẹ yọ lojiji lati ẹka ọfiisi ileeṣẹ to n ri ṣeto ẹkọ kari aye to wa ninu ọgba Oke-Ẹda.
O ni airi awọn panapana lasiko lo mu ki ina ọhun ran de ọfiisi ipolowo ọja redio ati tẹlifisan ipinlẹ Ondo atawọn ṣọọbu mi-in to ti sọṣẹ.
Akitiyan awọn to wa nitosi loru ọhun ni ko jẹ ki ina ọhun jo ọfiisi awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ati yara ile-ẹjọ Majisreeti to wa nibẹ gẹgẹ bo ṣe sọ.
Alakooso agba fun ileeṣẹ redio ati tẹlifisan ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Kunle Adebayọ, ni ni nnkan bii aago kan oru ni ọkan ninu awọn ọlọdẹ to n ṣọ ọfiisi awọn pe oun lati fi to oun leti.
O ni loju oun, adajọ agba nipinlẹ Ondo ati olori awọn oṣiṣẹ ni gbogbo ile nla mẹrẹẹrin fi jona kanlẹ patapta.
O ni loootọ lawọn padanu ọpọlọpọ nnkan, ṣugbọn ohun to dun mọ awọn ninu ju ni ti ẹmi ti ko ba iṣẹlẹ ina ọhun rin.
Awọn ileesẹ mi-in to ni wọn tun fara gba ninu ijamba yii ni ileesẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ-ọfẹ ati ibudo ede Faranṣe ẹka tipinlẹ Ondo.
Adebayọ ni lẹyin iwadii ni awọn too le fidi ohun to ṣokunfa ijamba naa mulẹ.