Ina jo ileetaja iyawo Ajimọbi n’Ibadan

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to mọ ohun to fa ijamba ina naa, ohun tawọn eeyan kan ri ni pe ina nla ṣẹ yọ ni ile itaja nla Grantex to wa ni Bodija, niluu Ibadan, to jẹ ti iyawo gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Florence Ajimọbi.

Ẹyin ile itaja naa la gbọ pe ina ọhun ti kọkọ bẹre, to si n ran lọ si iwaju ile itaja ọhun.

ALAROYE gbọ pe awọn ileesẹ panapana ti wa nibẹ lati pa ina ọhun ko ma baa di pe o ran lọ si awọn sọọbu to ku ati awọn ile to wa lagbegbe ibi iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa adigboluja wa nitosi lati ri i pe awọn ọmọọta ko lo anfaani iṣẹlẹ naa lati kọ lu ile itaja naa.

Ẹni to fi isẹlẹ yii to akọroyin wa leti sọ pe aya gomina telẹ yii atawọn mọlẹbi kan sare de sibi iṣẹlẹ naa lẹyin ti wọn kan si wọn.

Leave a Reply