Ina jo ilegbee awọn akẹkọọ Kwara Poli, ọpọ dukia lo segbe

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an yii, ni ina deede ṣẹ yọ ni ilegbee awọn ọmọ akẹkọọ Kwara Poli, to wa ni agbegbe Yakuba, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti ọpọ dukia si ṣegbe nibi iṣẹlẹ buruku naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ panapana ni Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, fi sita niluu Ilọrin, o ṣalaye pe ina ẹlẹntiriki to ṣẹju lo ṣokunfa ijamba ina ọhun ti dukia to le ni miliọnu mẹta si ṣegbe nibi jamba ina ọhun ti ajọ panapana si doola dukia to le ni miliọnu mẹwaa lọwọ ina.

Ọga agba ajọ panapana ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, fi ibanujẹ ọkan rẹ han si iṣẹlẹ buruku naa, o rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara ki wọn maa wa ni oju lalakan fi n sọri ni gbogbo ibi ti wọn ba wa, paapaa ju lọ ohun to ba jẹ mọ ọrọ ina.

 

Leave a Reply