Ina jo Ọja Tuntun niluu Ile-Ifẹ

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Inu Ibanujẹ nla lawọn oniṣowo ninu Ọja Tuntun to wa niluu Ile-Ifẹ, wa bayii latari ina ojiji to  deede ṣẹyọ ninu ọja naa ni nnkan bii aago kan oru, Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji oṣu kejila yii,  ti ọpọ dukia atawọn ọja olowo iyebiye si jona kọja sisọ.

Igba keji ree ti ina yoo ṣẹyọ lọja naa lọdun yii,  nitori ina ti kọkọ ṣọṣẹ nibẹrẹ ọdun yii lọja kan naa,ti awọn eeyan si ti ro pe iru nnkan bẹẹ ko ni i waye mọ. Ṣugbọn o ti tun ṣẹlẹ, afi ki Ọlọrun fi ofo rẹmi fun awon ti dukia won jona o.

Leave a Reply