Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Boya ka ni awọn eeyan ko lọọ maa gbọn epo nigba ti tanka epo to gbe bẹntiroolu fẹgbẹ lelẹ lagbegbe Oju-Irin, ni Lafẹnwa, Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni, boya ina to sọ lojiji, to si bẹrẹ si i jo hii-hii ko ba ma ṣẹlẹ.
Ṣugbọn awọn eeyan ko sowọ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to n kilọ, niṣe ni wọn lọọ n gbọn epo.
Lasiko ta a n kọ iroyin yii, awọn ẹṣọ alaabo TRACE ati FRSC ko ti i fidi ẹ mulẹ pe eeyan ku ninu iṣẹlẹ naa, ṣugbọn wọn ni to ba ṣe jẹ ṣa, awọn yoo fi to awọn akọroyin leti.
Gẹgẹ bi Babatunde Akinbiyi ti i ṣe Alukoro TRACE ṣe wi, o ni ni nnkan bii aago marun-un idaji ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni tanka to gbe epo naa ṣubu, lasiko to fẹẹ lọ si Rounder lati Oju-Irin, ni Lafẹnwa.
O ni bo ṣe ṣubu naa ni gbogbo epo to gbe bẹrẹ si i danu si titi.
Eyi lawọn eeyan to wa nitosi ri ti wọn fi lọọ n gbọn epo ọhun, nigba to ya ni ina ṣẹ yọ to si gba gbogbo agbegbe naa, to n jo kikan-kikan tawọn eeyan si n sa kiri.
Amọran tawọn TRACE gba awọn olugbe ibẹ ni pe ki wọn kọkọ kuro nitosi ina to n ran na, nitori o lewu gidi lati duro sibi ti ina bẹntiroolu ti n jo, ti eefin to ki si gba gbogbo agbegbe kan.
Sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ lo tẹle iṣẹlẹ yii, awọn to n dari ọkọ si lawọn wa nikalẹ lati kapa ẹ. Titi ta a fi pari iroyin yii ni ina ọhun ṣi n jo. Ọpọlọpọ ṣọọbu to wa nitosi iṣẹlẹ naa lọja Lafẹnwa lo si faragba a
Iroyin kan ti a ko fidi ẹ mulẹ sọ pe eeyan mẹrin lo jona ku ninu ina yii, ti wọn jona kọja idanimọ.