INEC ko awọn iwe-ẹri Adeleke ti ko han wa sile-ẹjọ, lagbẹjọro Oyetọla ba fariga

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ lasiko idibo gomina to kọja nipinlẹ Ọṣun ti sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ti a wa yii, latari bi ajọ eleto idibo INEC ṣe mu iwe-ẹri Gomina Ademọla Adeleke ti ko han wa fun wọn.

Iwe oloju-ewe mẹjọ ti igbakeji ọga agba kan lati ajọ INEC, Joan Arabs, ko wa si kootu lo jẹ tẹstimonia ti Adeleke gba nileewe Ẹdẹ Muslim Grammar School ati ti WAYẸẸKI.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ni kootu paṣẹ pe ki ajọ INEC ko awọn iwe-ẹri ti Adeleke fi dije dupo gomina ipinlẹ Ọṣun lọdun 2018 wa.

Nibi ijokoo ile l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun yii, lẹyin ti agbẹjọro olupẹjọ, Barisita Lateef Fagbemi, SAN, ẹni ti Barisita Akin Olujinmi, SAN, naa wa pẹlu rẹ, sayẹwo awọn iwe-ẹri naa lo sọ pe oju-ewe meji ko han daadaa nibẹ.

Fagbemi ṣalaye pe abala ti wọn kọ awọn maaki ti Adeleke gba si ko han rara, ati pe adirẹẹsi ileewe to ti gba tẹstimonia naa ko han.

Ṣugbọn agbẹjọro fun ajọ INEC, Ọjọgbọn Paul Ananaba, SAN, sọ pe awọn iwe ẹri naa ti han to, o rọ awọn agbẹjọro olupẹjọ lati jẹ ki igbimọ gba awọn iwe-ẹri naa wọle, niwọn igba ti wọn ti kọkọ sọ pe awọn ni ẹda (CTC) iwe -ẹri naa lọwọ ti wọn le fi kalẹ.

O ni oun ko ni i ta ko wọn ti wọn ba ko awọn ẹda iwe-ẹri ọrọ wọn silẹ.

Agbẹjọro fun Adeleke ati ẹgbẹ oṣelu PDP, Onyeachi Ikpeazu, SAN ati Dokita Alex Izinyon, SAN, sọ pe awọn kan han ninu iwe-ẹri naa. Wọn ni wọn ṣi le ṣatunṣe si i, bẹẹ ni wọn rọ olupẹjọ lati pe ẹlẹrii keji, ki ajọ INEC si lọọ ko awọn iwe-éri to han wa.

Asiko yii ni Ananaba parọwa si ile -ẹjọ pe ki wọn danu duro diẹ, ki oun le gba aworan awọn iwe-ẹri naa lori foonu lati olu ileeṣẹ ajọ INEC l’Abuja.

Lẹyin ti igbimọ naa pada jokoo, Ananaba fi awọn aworan iwe-ẹri to gba han kootu, ṣugbọn o sọ pe ko siyatọ ninu rẹ atawọn to ti wa niwaju ile-ẹjọ tẹlẹ.

O ni ki ile-ejọ sun ẹjọ naa siwaju ki ajọ INEC le gbe faili ti wọn ti ko awọn iwe-ẹri naa wa si kootu.

Ṣugbọn Fagbemi yari kanlẹ pe aṣẹ ile-ẹjọ ni pe ki wọn mu iwe-ẹri to han kedere wa, o ni o di dandan ki awọn olujẹjọ bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ọrọ naa, alaga igbimọ ọhun, Onidaajọ Tertsea Kume, sun igbẹjọ siwaju di ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun yii, fun ajọ INEC lati mu ojulowo iwe-ẹri Gomina Adeleke wa.

Leave a Reply