INEC mu iwe-ẹri Adeleke mi-in wa siwaju igbimọ igbẹjọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC, ti wọn jẹ olupẹjọ nile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ lasiko idibo gomina to kọja l’Ọṣun ti fi adagba ẹjọ riro wọn ti bayii.

Nibi ijokoo igbimọ naa to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun yii, wọn gba ojulowo Form CF001 ati gbogbo iwe-ẹri ti Gomina Ademọla Adeleke lo lasiko to n dije-dupo gomina Ọṣun lọdun 2018.

Awọn iwe naa ni ajọ eleto idibo INEC ko wa nipasẹ igbakeji ọga agba wọn kan, Joan Arabs. Lẹyin ti agbẹjọro fun olujẹjọ, Lateef Fagbemi, ṣayẹwo wọn tan ni igbimọ gba a gẹgẹ bii ẹsibiiti.

Ṣaaju ni agbẹjọro fun INEC, Henry Akunebo, ti sọ fun kootu pe onibaara oun gbe orijina faili ti gbogbo iwe-ẹri ti Adeleke ṣakọsilẹ rẹ sinu Form CF001 wa nibaamu pẹlu aṣẹ kootu nijokoo to kọja.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja naa ni ajọ INEC ti mu iwe-ẹri GCE ti Adeleke gba ni Ẹdẹ Muslim Grammar School, Ẹdẹ, wa si kootu, ṣugbọn balabala lo ri, ti ko si sẹni to riran ri nnkan to wa ninu ẹ, idi niyi ti awọn adajọ kootu naa fi paṣẹ pe ki ajọ INEC mu ojulowo awọn iwe-ẹri naa wa.

Agbẹjọro fun Adeleke to jẹ olujẹjọ keji, Barisita Niyi Owolade ati ti ẹgbẹ PDP, Alex Izinyon, SAN, sọ fun kootu pe awọn ti ṣayẹwo awọn orijina iwe-ẹri naa, wọn si han kedere yatọ si eyi ti wọn kọkọ mu wa.

Lẹyin ti Lateef Fagbemi SAN, yẹ awọn  iwe naa wo, o ni gbogbo nnkan to wa ninu rẹ lo ṣee ka, o si sọ pe oun fẹẹ ko wọn kalẹ nile-ẹjọ.

Bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro fun olujẹjọ ta ko kiko gbogbo awọn dọkumẹnti naa silẹ, sibẹ, o ni oun yoo fi awijare oun lori rẹ pamọ di igba akọsilẹ igbẹyin (final written address.)

Izinyon naa sọ pe ko yẹ ki igbimọ naa gba gbogbo dọkumẹnti naa, niwọn igba to jẹ pe oju-ewe meji pere ni ko han ninu eyi ti ajọ INEC kọkọ ko wa si kootu.

Ṣugbọn Fagbemi yari kanlẹ pe gbogbo ẹ ni ki igbimọ gba, niwọn igba to jẹ pe wọn ko ti i gba eyikeyii ninu awọn ti ajọ INEC kọkọ ko wa sile-ẹjọ.

Lẹyin atotonu abala mejeeji, awọn ọmọ igbimọ naa gba gbogbo orijina iwe ti ajọ INEC ko wa, wọn si pe e ni ẹsibiiti ‘File D’.

Nigba naa ni Fagbemi sọ fun ile-ẹjọ pe awọn olupẹjọ ti pari awijare wọn bayii.

Alaga igbimọ to n gbọ ẹjọ naa, Onidaajọ Tsetsea Kume, sun igbẹjọ si ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun yii, fun awọn olujẹjọ lati bẹrẹ awijare tiwọn naa.

 

Leave a Reply