Inu mi dun bile-ẹjọ ṣe da mi lare, ma a lọọ ṣiṣẹ lori orukọ mi ti wọn tabuku si – Kẹmi Adeọsun

Faith Adebọla

Ṣinkin bii ẹni jẹ tẹtẹ oriire ni inu minisita feto inawo nilẹ wa tẹlẹ, Abilekọ Kẹmi Adeọṣun, n dun l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, latari bile-ẹjọ giga ilu Abuja kan ṣe da a lare pe ko pọn dandan keeyan niwee ẹri jijẹ agunbanirọ ki tọhun too le dipo oṣelu eyikeyii mu.

Adajọ Taiwo Taiwo lo dajọ are ọhun ninu ẹjọ kan ti Abilekọ Adeọṣun pe ta ko awuyewuye to waye nipa iwe-ẹri National Youth Service Corps, ti wọn ni ko ni, ko si yẹ ko wa nipo minisita ilẹ wa.

Awuyewuye ọhun lo mu kobinrin naa kọwe fipo silẹ lọdun lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2018.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Taiwo sọ pe ẹni ọdun mejilelogun ni Adeọsun nigba to gboye jade ni Fasiti London, lorileede United Kingdom, nigba to si jẹ ilu oyinbo lọhun-un lo wa, ko si bo ṣe maa kopa ninu iṣẹ isinlu awọn agunbanirọ.

Igba ti olupẹjọ naa yoo fi pada si Naijiria, o ti le lẹni ọgbọn ọdun, eyi fihan pe o ti kọja ọjọ-ori ẹni to le kopa ninu eto isinlu naa.

Adajọ naa loun ṣakiyesi pe ofin ọdun 1979 ni Naijiria n lo lasiko to kawe tan, labẹ ofin naa, ọmọ orileede Britain ni Kẹmi nigba yẹn, ko si pọn dandan fun un lati kopa, tori ofin ọhun ko faaye gba keeyan jẹ ọmọ orileede meji papọ lẹẹkan naa.

Adajọ Taiwo fọba le e pe eeyan niwee ẹri NYSC tabi ko ni i ko sọ pe ki wọn maa yan an sipo oṣelu tabi minisita, iyẹn o si dena ẹnikẹni to ba fẹẹ dije fun ileegbimọ aṣofin.

O ni ile-ẹjọ faṣẹ si awọn ibeere mẹrẹẹrin ti olupẹjọ naa beere, kootu naa si da a lare.

Bi wọn ṣe n pari igbẹjọ naa ni Abilekọ Kẹmi Adeọṣun ti fi atẹjade kan lede nipa bi inu rẹ ṣe dun to lori bi Ifa ẹjọ to pe ọhun ṣe fọ’re fun un.

Adeọsun ni ohun to dun mọ oun ninu ju lọ ni bile-ẹjọ ṣe paṣẹ pe ki i ṣe ọran-an-yan koun mu iwe-ẹri fasiti oun wa, tabi koun kopa ninu iṣẹ aṣesinlu awọn agunbanirọ koun too tọ tun fun iyansipo gẹgẹ bii minisita.

“Idajọ yii ti da mi lare kuro ninu abawọn buruku to ba ba mi lori ọrọ yii. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba, awọn mọlẹbi mi, awọn ọrẹ mi,  lọọya mi, Oloye Wọle Ọlanipẹkun ati gbogbo ẹyin ololufẹ mi tẹ ẹ daniyan nipa mi nigba tọrọ yii ṣẹlẹ lọjọsi.”

Leave a Reply