Inu oṣu Keje yii ni Ismail tẹwọn de to tun fi lọọ ji ọkada gbe ni Kwara

Ibrahim Alagunmu

Akolo ajọ ẹsọ alaabo sifu difẹnsi, ẹka tipinlẹ Kwara, ni Wasiu Ismail ati awọn adigunjale ẹgbẹ rẹ, Abifarin Sunday ati Tayọ Elija, wa bayii. Lẹyin ti ọmọkunrin yii lo ọdun meji lẹwọn fun ẹsun ole jija ni wọn lọọ ji ọkada niluu Oro, nipinlẹ Kwara.

Nigba ti Alukoro ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọlasunkanmi Ayẹni, n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Aje, Mọnde, niluu Ilọrin, o ni wọn mu eeyan meji niluu Oro, wọn si ko awọn yooku niluu Ogbomọsọ. Ayẹni ni ọkan lara awọn afurasi yii, Wasiu Ismail, ẹni ọgbọn ọdun, to ṣẹṣẹ tẹwọn de ni ọjọ keji, osu Keje, ọdun yii, ni ọwọ tẹ niluu Oro, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara, fẹsun pe o ji ọkada gbe. Ayẹni tẹsiwaju pe Ismail jẹwọ pe oun ṣẹṣẹ dari ẹwọn ni Plasma TV lo lọọ gbe ti wọn fi ran an lẹwọn ọdun kan aabọ, kete to dari de lati ẹwọn lo bẹrẹ jiji ọkada nile onile niluu Ilọrin ati Oro

Ọkada mẹta ni wọn ri gba lọwọ Ismail atawọn adigunjale ẹgbẹ rẹ, to si jẹ pe ọpọ ọlọkada ni wọn maa n ṣe iku pa ki wọn too ri ọkada wọn ji gbe, ti wọn si maa n wọ ile onile loru lati ji ọkada.

Ismail sọ pe ọkan ninu awọn ẹgbẹ oun, Ogunbiyi Johnson, lati ilu Osogbo, lo maa n wa onibaara ti yoo ra ọkada toun ba ji gbe, ti wọn si maa n ta ọkọọkan ni ẹgbẹrun lọna aadọje Naira (#130, 000).

Lukman Rasheed, ẹni ọdun melilelogoji, wa lara awọn afurasi ti wọn sọ pe onibara lasan lo maa n ba a wa . Niṣe ni Ismail pe e lori foonu pe ọmọ yahoo kan lo wa ni ahamọ ajọ EFCC, to si fẹẹ fi owo gba ara rẹ silẹ lo ṣe fẹẹ ta ọkada ọhun

 

 

Ayẹni ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii, awọn afurasi mejeeje yoo foju ba Ile-ẹjọ.

Leave a Reply