Inu oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, ni Tinubu yoo sọ boya yoo dupo aarẹ-Faṣọla

Faith Adebọla, Eko

 Loootọ lo jẹ pe ẹnu onikan la ti n gbọn pọ-un, ṣugbọn kawọn eeyan too le gbọ latẹnu agba-ọjẹ oloṣelu ilu Eko ati Adari apapọ fun ẹgbẹ oṣẹlu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, boya yoo jade dupo aarẹ Naijiria lọdun 2023 tabi ko ni i jade, o di ọsu ki-in-ni, ọdun to n bọ (2022) ki Jagaban tilẹ Borgu too fẹnu ara ẹ sọ.

Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, to jẹ Minisita fun iṣẹ ode ati eto ile gbigbe nilẹ wa, Ọgbẹni Babatunde Raji Faṣọla, lo sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lori Tẹlifiṣan Channels, nigba tawọn oniroyin n fọrọ wa a lẹnu wo.

Wọn beere lọwọ Faṣọla pe ta lo maa ṣatilẹyin fun lati bọ sipo aarẹ lọdun 2023, lọkunrin naa ba fesi, o ni:

“Ni temi o, titi di bi mo ṣe n sọrọ yii, ẹnikẹni o ti i sọ fun mi pe oun fẹẹ dupo aarẹ Naijiria o. Awọn eeyan ni wọn ṣi n sọ pe awọn fẹ ki lagbaja ṣe e, awọn fẹ ki tamẹdu di aarẹ, tabi ki lakaṣegbe jade. Ko ti i sẹni to fẹnu ara ẹ sọ pe oun ṣetan, oun fẹẹ dije, tori asiko iyẹn o ti i to.

Ṣe ẹ mọ pe a ki i gba ẹnu olokunrun joogun, mi o le sọrọ fẹnikan, afi ki ẹni to ba fẹẹ dije jade sita funra ẹ, ko si kede pe ‘emi lagbaja o, mo fẹẹ di aarẹ Naijiria.’

O maa n dun mi nigba mi-in ti ẹni to fẹẹ dije ba n sọ pe ‘awọn eeyan mi ni ki n jade,’ mo ro pe bo ṣe yẹ ko ri ni pe ki onitọhun funra ẹ ti yẹ ara ẹ wo, ko ri i pe oun ‘kaju ẹ’ lati sọ fawọn eeyan pe ‘ẹ gbe iṣoro yin wa, ma a ba yin yanju ẹ, ẹ da mi da a, ẹ lọọ sun ni tiyin.’

Ni tọrọ Aṣiwaju (Tinubu) tẹ ẹ beere, mo ṣi ri wọn lọsẹ to kọja yii, wọn o sọ fun mi pe awọn fẹẹ jade dupo, gbogbo ohun ti mo le ranti pe wọn sọ nipa ẹ ni pe o di oṣu January kawọn too jẹ kawọn eeyan mọ ero ọkan awọn.”

Wọn beere lọwọ Faṣọla boya o ti beere erongba Tinubu lọwọ oun funra ẹ ri, o ni “rara, mi o bi wọn leere, mo kan lọọ bi ki wọn pe ‘ṣe ara le ni’. Tinubu funra ẹ ti fi atẹjade lede pe January loun maa sọrọ. Ẹ jẹ ka mu suuru digba yẹn, ka gbọrọ latẹnu ọlọrọ.”

Wọn tun beere lọwọ Faṣọla boya oun naa nifẹẹ lati jade dupo aarẹ, o ni iṣẹ nla ni ipo aarẹ, oun o si jowu awọn ti wọn wa nipo naa, koda, o loun o jowu awọn ti wọn fẹẹ dije fun ipo ọhun pẹlu.

Leave a Reply