Inu otẹẹli lawọn SARS pa ọmọ mi si n’Iwoo, wọn tun ji miliọnu mẹrin naira rẹ lọ-Ayinla

Florence Babasola, Oṣogbo

Barisita Fatai Ajani to jẹ agbẹjọro fun baba agba kan, Ayinla Rasheed, to tun n ṣoju fun ẹni to ni otẹẹli Ile Labọ Sinmi Oko, niluu Iwo, lo kọkọ fara han niwaju igbimọ tijọba ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lori wahala awọn ọlọpaa loni-in.

Ninu iwe ẹsun ti ọkunrin agbẹjọro yii mu wa ni Alagba Rasheed ti ṣalaye bi awọn ọlọpaa SARS ṣe yinbọn pa ọmọ rẹ, Ismail, sinu otẹẹli naa, ti wọn si gbe miliọnu mẹrin naira to fẹẹ fi ra agbo lọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ilu Ọrẹ, nipinlẹ Ondo, ni Ismail n gbe pẹlu iyawo meji atawọn ọmọ marun-un to bi. Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje, ọdun yii, lo gbera lati lọọ ra ẹran agbo nilẹ Hausa fun ọdun Ileya.

“Nigba to fi maa de ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, o ti di aago mẹsan-an aabọ alẹ, o si pinnu lati sun sinu otẹẹli naa. Inu otẹẹli yii kan naa ni awọn SARS meji ti inagijẹ wọn n jẹ Arẹ ati Oodua n gbe lọfẹẹ, nitori pe awọn ni wọn n ṣeto aabo fawọn to n kọja loju ọna Iwo si Ibadan nigba yẹn.

“Nigba to di aago mẹta aabọ oru ni ọkan lara awọn ọlọpaa SARS yii lọọ sọ fun manija otẹẹli naa, Afeez Tella Adio, pe awọn ti pa ọkan lara awọn ole ti wọn fẹẹ ṣọṣẹ ninu otẹẹli naa.

Manija sare wọnu yara Ismail, o si ba a ninu agbara ẹjẹ, o ni ọrọ kan ṣoṣo toun ba lẹnu Ismail ni pe ‘ọmọ ole, o ti pa mi’. Nigba ti Alhaji Ayọ Dauda Adigun to ni otẹẹli naa yoo fi debẹ, DPO agbegbe naa ati awọn ọlọpaa mi-in ti debẹ.

“Ọkan lara awọn ọrẹ Ismail to mọ nipa irinajo rẹ lọjọ naa lo sọ fun awọn mọlẹbi rẹ pe owo to wa lọwọ rẹ lọjọ naa le ni miliọnu mẹrin naira”.

Latari idi eyi, olupẹjọ beere fun miliọnu mẹfa naira fun ẹni to ni otẹẹli, nitori iṣẹlẹ naa ti le ọpọ onibaara sẹyin nibẹ. O ni kileeṣẹ ọlọpaa da miliọnu mẹrin naira ti wọn gba lọwọ oloogbe pada, ki wọn si san miliọnu lọna ọgọrun-un fun itọju awọn iyawo ati ọmọ ti oloogbe fi saye lọ.

Alaga igbimọ naa, Onidaajọ Akin Ọladimeji sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun yii.

Ṣaaju ni Ọladimeji ti ṣeleri pe igbimọ ẹlẹni-mẹtala naa ko ni i ṣegbe lẹyin ẹnikẹni.

Leave a Reply