Inu sọọsi ni Bayọ wa to ti n gbadura, lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pe e jade, wọn si pa a n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n rẹ ara wọn danu bii ila niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, bi wọn ti n para wọn ni wọn n pa awọn ti ko mọwọ mẹsẹ lati ọsẹ to kọja. Ẹmi to ti bọ n lọ bii rẹrẹ. Ni bayii, wọn ti tun ṣeku pa ọdọmọkunrin kan ti ọpọ eeyan mọ si Bayọ Lala, lasiko to n jọsin lọwọ ni ṣọọṣi Ridiimu to wa ni agbegbe Basin, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe owurọ ọjọ Aiku, Sunnde, ọṣẹ yii, niṣẹlẹ naa waye. Bayọ n gbadura lọwọ ninu ṣọọṣi ni awọn kan deede pe e lori aago pe ko maa bọ nita, ni kete to jade sita ni wọn rọjo ibọn lu u, ti wọn si ri pe o ku patapata ki wọn too fi i silẹ ninu agbara ẹjẹ, ti wọn si ba tiwọn lọ, iro ibọn ti awọn olujọsin gbọ ninu ṣọọṣi da ibẹru bojo silẹ ti ẹlomiran si fẹrẹ maa tọ sara, ṣugbọn lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn ni awọn eeyan naa lọ tan ni awọn ero ile-ijọsin naa too jade sita, ti wọn si ba Bayọ ninu agbara ẹjẹ. Wọn sare gbe e lọ si ileewosan olukọni Fasiti ilu Ilọrin, ṣugbọn ẹpa o boro mọ, o ti jade laye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa, o ni iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, awọn yoo si fi oju aṣebi han ni gbangba.

Ija agba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji ọhun, Ẹyẹ ati ẹgbẹ Aiye ti n waye lati bii ọjọ diẹ sẹyin, ti wọn si n pa ara wọn. Ọpọ awọn ti ko mọ nnkan kan nipa rẹ ni wọn si ti pa nifọna-fọnṣu.

Leave a Reply