Ipade alaafia awọn oludije sipo gomina ẹgbẹ APC Ondo fori sanpọn

 

Iyiade Oluṣẹyẹ, Akurẹ

Afaimọ ki fa-a-ka-ja-a to n fojoojumọ ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo ma ṣe akoba fun ẹgbẹ naa bi awọn oludije naa ko ba gba alaafia laaye.

Ni ọjọ Ẹti, Furaide, ni awọn agbaagba ẹgbẹ yii pe ipade kan lati mu ki alaafia jọba laarin awọn oludije naa, ki ẹgbẹ wọn le wa ni iṣọkan ni ipalẹmọ fun eto idibo gomina to maa waye ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Gomina ipinlẹ Niger, Mallam Sani Bello, lo dari ipade ọhun to waye ni Heritage hotel, niluu Akurẹ. Ṣugbọn marun-un pere ninu awọn oludije naa lo yọju, awọn meje yooku ko ba wọn kopa nibi ipade naa.

ALAROYE gbọ pe awọn eeyan naa ko yọju nitori wọn ni wọn ti n gbọ finrin finrin pe o ṣee ṣe ki awọn igbimọ naa ni ki wọn juwọ silẹ fun ẹni kan ninu wọn, ki awọn to ku si ṣatilẹyin fun un.

Awọn kan ninu wọn si ti leri pe awọn ko ni i si nibi ipade alaafia kankan pẹlu gomina Akeredolu to n ṣakoso ipinlẹ naa lọwọ, toun naa si fẹẹ dije dupo gomina ọhun lẹẹkeji.

Gomina Akeredolu, Sọla Iji, Ifẹ Oyedele, Bukọla Adetula ati Jimi Odimayọ nikan lo yọju sibi ipade naa ninu awọn oludije mejila ti wọn ti ṣayẹwo fun lati kopa ninu eto idibo abẹle ti yoo waye laipẹ.

Leave a Reply