Ipade apapọ ẹgbẹ APC yoo waye ninu oṣu keji-Awọn gomina

Jọkẹ Amọri

Lẹyin ipade ti wọn tilẹkun mọri ṣe niluu Abuja lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ẹgbẹ awọn gomina to jẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn pera wọn ni The Progressive Governors Forum, ti kede pe ipade apapọ ẹgbẹ naa, nibi ti wọn yoo ti yan awọn oloye ẹgbẹ yoo waye ninu oṣu keji, ọdun ta a wa yii.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i sọ ọjọ kan pato ti ipade naa yoo waye ninu oṣu keji ti wọn sọ ọhun, sibẹ, Gomina ipinlẹ Kebbi, Aliyu Bagudu, to jẹ alaga awọn gomina yii sọ fawọn oniroyin niluu Abuja lọjọ Aiku naa pe ipade apapọ ẹgbe ọhun yoo waye.

O fi kun un pe igbimọ alamoojuto pataki ẹgbẹ naa ti yoo ri si ipade ọhun, iyẹn (Caretaker Etra-ordinary Convention Committee) ni o laṣẹ lati kede ọjọ ti awọn maa mu.

Lara ohun to ni awọn jiroro le lori nibi ipade naa nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ipade gbogbogbo ẹgbẹ ọhun. Bagudu ni ti awọn eeyan ko ba gbagbe, oun pe ipade oniroyin lẹyin tawọn ṣe ipade pọ pẹlu Aarẹ Buhari ninu oṣu kọkanla, ọdun to kọja, nibi tawọn ti fẹnuko pe inu oṣu keji ni ipade naa yoo waye.

Bakan naa lo ni awọn tun lo anfaani ipade yii lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe ko si iyapa laarin awọn gomina ẹgbẹ APC. Eyi lo ni o fidi mulẹ pẹlu iye awọn gomina to wa sibi ipade ọhun.

Bakan naa lo ni awọn to wa nibi ijokoo ipade naa fi atilẹyin wọn han fun isakoso igbimọ adele ti Buni n dari, to fi mọ awọn ọmọ igbimọ naa meji, iyẹn Gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla ati Gomina ipinlẹ Niger, Muhammed Bello.

Bagudu ni iṣẹ takuntakun lawọn ọmọ igbimọ naa n ṣe, bi wọn si ti n ṣiṣẹ wọn mu iwuri dani gidigidi, bẹẹ ni wọn ti tun gba ọpọlọpọ awọn mi-in sinu ẹgbẹ APC.

Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, lawọn gomina bii mẹrindinlogun yii pade nile ijọba ipinlẹ Kebbi to wa ni Asokoro District, niluu Abuja. Ohun ti wọn ni ipade ọhun, ninu eyi ti Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, Ogun, Dapọ Abiọdun, Nasir El-Rufai ti Kaduna, Yahaya Bello lati Kogi, Abubakar Sanni Bello lati Niger ati bẹẹ bẹẹ lọ wa ni lati fẹnuko lori boya ipade apapọ ẹgbẹ naa yoo waye ninu oṣu keji ọdun yii.

Tẹ o ba gbagbe, Aarẹ Muhammadu Buhari ti figba kan sin awọn ẹgbẹ naa ni gbẹrẹ ipakọ pe ti wọn ko ba mura, ki wọn si ṣepade gbogbogboo yii lati yan awọn adari tuntun, o ṣee ṣe ki egbẹ PDP gbapo aarẹ mọ wọn lọwọ nibi ti wọn ba ti n ṣe yọdẹyọdẹ, ti wọn si fọwọ yọbọkẹ mu ohun gbogbo.

Leave a Reply