Ipalẹmọ igbeyawo lawọn ololufẹ yii n ṣe lọwọ ti wọn fi sun ti wọn o ji mọ  

Ipalẹmọ igbeyawo lawọn ololufẹ yii n ṣe lọwọ ti wọn fi sun ti wọn o ji mọ

Ọkunrin ati obinrin ti ẹ n wo yii ko si laye mọ, Ọjọbọ to kọja ni awọn araale ba oku wọn ni yara, bẹẹ alaafia ni wọn wọle sun lalẹ Ọjọruu, afi bi ilẹ ṣe mọ ti wọn ko ji saye mọ nile wọn to wa ni Naza, Owerri, nipinlẹ Imo.

Ololufẹ lawọn mejeeji gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ipalẹmọ igbeyawo ni wọn n ṣe lọwọ paapaa, ohun ti ọkọ torukọ ẹ n jẹ Chidiebere Anusiem, tori ẹ wale lati Dubai to ti n ṣiṣe aje niyẹn. Iyawo ni wọn pe orukọ tiẹ ni Amara Ehirim, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) nigba ti ọkọ jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (32)

Gẹgẹ bi ẹka iroyin Guardian ṣe ro o, wọn ni akẹkọọ gboye ni Amara, ṣugbọn tii kan to jẹ tewe-tegbo lo n ta tipẹ. Wọn ni tii naa lo fi ran ara ẹ nileewe giga lẹyin ti iya rẹ ku, ti baba rẹ si lọọ fẹ obinrin mi-in, to gbagbe Amara ati awọn aburo rẹ yooku.

Bo ti n kawe naa ni wọn lo n ta tii yii, awọn eeyan si ti mọ ọn daadaa pẹlu ẹ. Chidiebere ti wọn ti jọ n fẹra wọn tipẹ waa ṣetan lati ṣegbeyawo pẹlu rẹ lo ṣe wale lati Dubai, afi bi wọn ṣe wa lẹnu ipalẹmọ ti iku ojiji de.

Lori ohun to fa iku ọhun, awọn alajọgbele wọn sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ eefin jẹnẹretọ ni wọn fa simu mọju, o si ṣee ṣe ko jẹ ounjẹ ti wọn jẹ lalẹ lo gbodi lara wọn.

Ṣugbọn ẹnikan ninu awọn eeyan naa sọ pe ki i ṣe jẹneretọ, o ni wọn ko ṣẹṣẹ maa gbe jẹnẹretọ wọn sibi ti wọn gbe e si, bẹẹ ni awọn nikan kọ ni wọn jẹun lalẹ Ọjọruu.

O ni wọn lọọ ṣe faaji nibi kan pẹlu awọn eeyan mi-in to jẹ ọrẹ wọn, ounjẹ kan naa ni gbogbo wọn jẹ nibẹ, awọn iyẹn ko ṣe ku mọju.

Awọn ọlọpaa tilẹ mu ọrẹ ọkọ iyawo yii kan, ti wọn ni wọn fura si i lori iku wọn, ṣugbọn wọn ti pada fi i silẹ nigba ti wọn ko ri nnkan kan to le jẹ ki wọn fura si i.

Ṣaa, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iku awọn ololufẹ meji yii gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Imo, Mike Abattam, ṣe fidi ẹ mulẹ.

Leave a Reply