Dada Ajikanje
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti sọ pe ṣiṣeto aabo to mọ iyan lori ati atunto orileede yii lo ṣe pataki ju ẹni ti yoo wa ni ipo aarẹ lorileede wa lọ.
Lasiko to n fun awọn ikọ Amọtẹkun ni kọkọrọ ọkọ mẹtalẹlọgbọn ati ọkada mẹrindin-ni-irinwo (396) to pese fun wọn lo sọrọ naa di mimọ.
Gomina yii waa sọko ọrọ lu awọn to ni wọn n sare kaakiri Naijiria nitori erongba ati di aarẹ, o ni yoo too ye iru awọn oloṣelu bẹẹ.
Makinde ni, ‘‘Mo gbọ pe awọn aṣaaju wa kan nidii oṣelu n sare kiri pe awọn fẹẹ di aarẹ orileede yii, ṣugbọn lero temi, ohun ta a nilo lasiko yii ni ka pese aabo to nipọn fawọn eeyan wa, ki a si ṣe atunto orileede yii. Ki Ọlọrun pa awọn ti wọn n sare lati di aarẹ yii mọ di ọdun 2022, nigba naa la oo mọ boya ipo aarẹ lati ilẹ Yoruba ni a nilo ni abi atunto ilẹ wa.’’