Ipinlẹ Kwara ni wọn ti ri ọba Ekiti ti wọn ji gbe gba pada

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ọbadu tilu ilẹmẹṣọ-Ekiti, Ọba David Oyewumi, ti gba ominira lọwọ awọn ajinigbe to gbe e l’Ọjọbọ, Tọsidee to kọja, ninu aafin ẹ.

ALAROYE royin pe nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ naa lawọn agbebọn ọhun fo fẹnsi aafin wọle, ti wọn si kọkọ fiya jẹ gbogbo awọn ti wọn ba nibẹ ki wọn too gbe kabiyesi lọ.

Lẹyin eyi la gbọ pe wọn beere fun miliọnu lọna ogun naira ki wọn too le fi ori-ade ọhun silẹ, ko too waa di pe o pada gba ominira bayii.

Adari ikọ Amọtẹkun l’Ekiti, Ọgagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, ṣalaye pe ilu kan to n jẹ Obbo Ayegunlẹ, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, ni ikọ naa ti gba kabiyesi lọwọ awọn to ji i gbe pẹlu iranlọwọ awọn fijilante ipinlẹ naa.

Kọmọlafẹ ni, ‘Nigba ta a de inu igbo, a tọpasẹ ibi ti wọn gbe kabiyesi, awa atawọn fijilante Kwara, bẹẹ la lanfaani lati gba kabiyesi silẹ ninu igbo Obbo-Ile.

‘Ko sẹni to sanwo itusilẹ kankan. A ti mu wọn wale, wọn si n gba itọju lọwọ.’

Ninu alaye tiẹ, ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro ọlọpaa Ekiti sọ pe kabiyesi naa ti pada sọdọ awọn mọlẹbi ẹ lẹyin igbiyanju awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ alaabo mi-in, o si n gba itọju lọwọ latari ohun toju ẹ ri.

Leave a Reply