Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lẹyin nnkan bii oṣu meji ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe Ọlalẹyẹ Sunday Falẹyẹ wa sipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii kọmiṣanna, wọn tun ti gbe okunrin naa kuro bayii.
Ko si ẹni to mọ idi ti iṣipopada Falẹyẹ, ẹni ti wọn gbe wa loṣu Kẹwaa, ọdun yii, fi ya kiakia bẹẹ.
Olu ileeṣẹ ọlọpaa l’Abuja la gbọ pe wọn gbe Falẹyẹ lọ gẹgẹ bii Kọmiṣanna ni ẹka iṣakoso (CP Admin).
Ni bayii, wọn ti gbe ẹlomi-in wa sipinlẹ Ọṣun, oun naa si ni Patrick Kẹhinde Longẹ.
Ọdun to kọja ni Patrick ati iyawo rẹ di kọmiṣanna ọlọpaa, ọdun 1990 lawọn mejeeji si wọ ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn too ri ara wọn nileewe ẹkọṣẹ ọlọpaa ni Kano.