Ipinlẹ Ogun ni Mumini ti ji owo lanledi rẹ, Oṣogbo lọwọ awọn Amọtẹkun ti tẹ ẹ 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ awọn ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin kan, Mumini Saheed, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, niluu Oṣogbo, miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba naira (#1.2m), awọn nnkan ẹṣọ ara ati oogun abẹnugọngọ ni wọn ba lọwọ ẹ.

Ọsan oni ni wọn ri i ti Mumini n rin regberegbe kaakiri ninu ileewosan ijọba to wa ni Aṣubiaro, niluu Oṣogbo, pẹlu baagi dudu kan to gbe lọwọ, nigba ti wọn beere ibi to n lọ, kabakaba lo n sọ lẹnu, idi niyi ti wọn ṣe fi ọwọ lile mu un.

Bayii ni Mumini bẹrẹ si i ka boroboro. O ni inu yara lanledi oun to n gbe lagbegbe Local Government Secretariat, niluu Shagamu, nipinlẹ Ogun, loun ti ji miliọnu kan ẹgbẹta naira (#1.6m) to wa ninu baagi naa ninu oṣu keji, ọdun yii.

Owo lanledi to ji

Mumini jẹwọ pe ẹni ọgọrin ọdun ni lanledi oun yẹn, ati pe oun loun maa n tọju ẹ, idi si niyẹn toun fi lanfaani si yara ẹ. O ni obinrin naa buru pupọ, ko si fi owo mọ awọn ọmọ to bi ninu, idi niyẹn toun fi pinnu lati ja a lole.

Ṣugbọn ko pẹ to sa kuro niluu Shagamu ni ajakalẹ arun Korona bẹrẹ, o wa n sa kaakiri laarin ilu Oṣogbo ati Ibadan, o ni oun ti na ẹgbẹrun lọna irinwo naira ninu owo naa, oun si ti pinnu pe oun yoo gba ile ninu ẹ ti igbele Koronafairọọsi yii ba ti kọja.

Bakan naa ni awọn Amọtẹkun ba fọto oyinbo kan ninu ẹru rẹ, o si sọ pe ẹnikan lo mu fọto naa waa foun fun adura pataki.

Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, wọn ti fa a le awọn ọlọpaa Ọja-Ọba Division lọwọ fun iwadii to peye.

Nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, Alakooso ikọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Alhaji Amitolu Shittu, kilọ fun gbogbo awọn oniwa ibajẹ lati yẹra nipinlẹ Ọṣun, nitori ṣe ni aṣiri wọn a maa tu lẹyọkọọkan.

 

 

Leave a Reply