Ipinnu awọn gomina Guusu lati fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba ta ko ofin ilẹ wa- Malami

Faith Adebọla

 Ijọba apapọ ti yinmu sawọn to n patẹwọ fawọn gomina ipinlẹ Guusu ilẹ wa lori ipinnu ti wọn ṣe laipẹ yii lati fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba, wọn ni ipinnu naa ko daa, ko bofin mu, awọn o si ṣatilẹyin fun un rara.

Minisita feto idajọ ati Onidaajọ agba ilẹ wa, Ọgbẹni Abubakar Malami, lo sọrọ yii nigba to n dahun ibeere lori eto ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, lori iṣẹlẹ ọhun.

Malami ni bawọn gomina Guusu ṣe fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba yii ko yatọ si kawọn gomina ipinlẹ Ariwa naa dide, ki wọn lawọn fofin de tita ẹya ara mọto, paati mọto ni gbangba lawọn ipinlẹ awọn, ṣe iyẹn maa bofin mu?

Malami sọ pe: “Ọrọ nipa ofin ati ẹtọ la n sọ yii, gẹgẹ bi iwe ofin ilẹ wa ṣe la a kalẹ. Ṣe ẹnikan le fẹtọ awọn ọmọ Naijiria du wọn ni?

Fun apẹẹrẹ, bi wọn ṣe fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba yii ko yatọ si kawọn gomina ipinlẹ Ariwa naa dide, ki wọn lawọn fofin de tita ẹya ara mọto ni gbangba lawọn ipinlẹ Oke-Ọya, ṣe iru ofin bẹẹ maa fẹsẹ mulẹ? Ṣe awọn gomina Oke-Ọya naa le lawọn o fẹ kẹnikẹni ta paati mọto ni gbangba nipinlẹ awọn?

Lori ọrọ yii, to ba jẹ ti ẹtọ araalu labẹ ofin ni, ohun to yẹ ki wọn ṣe ni, boya ki wọn kọkọ ṣiṣẹ lori ayipada ati atunṣẹ ofin ilẹ wa na. Ofin ilẹ wa lo fun awọn araalu lominira ati ẹtọ lati rin falala, ki wọn yan fanda bo ṣe wu wọn. Ti iru irin ati iyan-fanda bẹẹ ko ba tẹ ẹni kan lọrun, niṣe ni tọhun maa kọkọ gba ile aṣofin lọ, ti yoo si sọ fun wọn pe ki wọn ba oun fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba o, boya onitọhun le ri atilẹyin awọn aṣofin lori erongba rẹ.

Kawọn gomina kan dide ki wọn si ro pe awọn le ṣe ipinnu to maa jin ofin ilẹ wa lẹsẹ lọna kan tabi omi-in bii eyi ti wọn ṣe yii, o lewu, o si le ṣakoba gidi.”

Malami tun sọ pe ijọba apapọ ti n fẹsọ yiri ipinnu tawọn gomina naa ṣe nipade wọn ọhun wo, ijọba yoo si gbe igbeṣẹ to bofin mu lori ẹ.

Leave a Reply